-
Mátíù 28:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Wò ó! Jésù pàdé wọn, ó sì sọ pé: “Ẹ ǹlẹ́ o!” Wọ́n sún mọ́ ọn, wọ́n di ẹsẹ̀ rẹ̀ mú, wọ́n sì tẹrí ba* fún un.
-
-
Jòhánù 20:19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Nígbà tí ọjọ́ ti lọ lọ́jọ́ yẹn, ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, tí ilẹ̀kùn ibi tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn wà sì wà ní títì pa torí pé wọ́n ń bẹ̀rù àwọn Júù, Jésù wá, ó dúró ní àárín wọn, ó sì sọ fún wọn pé: “Àlàáfíà fún yín o.”+
-
-
1 Kọ́ríńtì 15:4-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 àti pé a sin ín,+ bẹ́ẹ̀ ni, pé a jí i dìde+ ní ọjọ́ kẹta+ bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ;+ 5 àti pé ó fara han Kéfà,*+ lẹ́yìn náà, àwọn Méjìlá náà.+ 6 Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han èyí tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) àwọn ará lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo,+ púpọ̀ nínú wọn ṣì wà pẹ̀lú wa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn díẹ̀ ti sùn nínú ikú. 7 Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han Jémíìsì,+ lẹ́yìn náà, gbogbo àpọ́sítélì.+
-