-
Léfítíkù 11:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 “‘Àmọ́ ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn ẹran yìí tó ń jẹ àpọ̀jẹ tàbí àwọn tí pátákò wọn là: ràkúnmí máa ń jẹ àpọ̀jẹ, àmọ́ pátákò rẹ̀ kò là. Aláìmọ́ ló jẹ́ fún yín.+
-
-
Léfítíkù 11:13-20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 “‘Àwọn ẹ̀dá tó ń fò tí ẹ máa kà sí ohun ìríra nìyí; ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ wọ́n, torí ohun ìríra ni wọ́n jẹ́: ẹyẹ idì,+ idì ajẹja, igún dúdú,+ 14 àwòdì pupa àti gbogbo onírúurú àwòdì dúdú, 15 gbogbo onírúurú ẹyẹ ìwò, 16 ògòǹgò, òwìwí, ẹyẹ àkẹ̀ àti gbogbo onírúurú àṣáǹwéwé, 17 òwìwí kékeré, ẹyẹ àgò, òwìwí elétí gígùn, 18 ògbùgbú, ẹyẹ òfú, igún, 19 ẹyẹ àkọ̀, gbogbo onírúurú ẹyẹ wádòwádò, àgbìgbò àti àdán. 20 Kí gbogbo ẹ̀dá abìyẹ́ tó ń gbá yìn-ìn,* tí wọ́n ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn jẹ́ ohun ìríra fún yín.
-
-
Diutarónómì 14:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 “O ò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tó ń ríni lára.+
-