3 Ọkùnrin kan wà tó jẹ́ Farisí, Nikodémù+ ni orúkọ rẹ̀, alákòóso àwọn Júù ni. 2 Ẹni yìí wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní òru,+ ó sì sọ fún un pé: “Rábì,+ a mọ̀ pé olùkọ́ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọ́, torí kò sẹ́ni tó lè ṣe àwọn iṣẹ́ àmì+ tí ò ń ṣe yìí, àfi tí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú rẹ̀.”+