33 Èmi gan-an ò mọ̀ ọ́n, àmọ́ Ẹni tó rán mi láti fi omi batisí sọ fún mi pé: ‘Ẹnikẹ́ni tí o bá rí tí ẹ̀mí ń sọ̀ kalẹ̀, tó sì bà lé,+ òun ni ẹni tó ń fi ẹ̀mí mímọ́ batisí.’+
17 ‘“Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ni Ọlọ́run wí, “èmi yóò tú lára ẹ̀mí mi sára onírúurú èèyàn,* àwọn ọmọ yín lọ́kùnrin àti lóbìnrin yóò máa sọ tẹ́lẹ̀, àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín yóò máa rí ìran, àwọn àgbà ọkùnrin yín yóò sì máa lá àlá,+