ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìṣe 13:50
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 50 Àmọ́ àwọn Júù ru àwọn obìnrin olókìkí tó bẹ̀rù Ọlọ́run àti àwọn ọkùnrin sàràkí-sàràkí ìlú náà sókè, wọ́n gbé inúnibíni+ dìde sí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, wọ́n sì jù wọ́n sí ẹ̀yìn ààlà ìlú wọn.

  • 1 Kọ́ríńtì 15:30, 31
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 30 Kí nìdí tí a fi ń wà nínú ewu ní wákàtí-wákàtí?*+ 31 Ẹ̀yin ará, ojoojúmọ́ ni mò ń dojú kọ ikú. Èyí dájú bí ayọ̀ tí mo ní lórí yín ṣe dájú, èyí tí mo ní nínú Kristi Jésù Olúwa wa.

  • 2 Kọ́ríńtì 11:23-26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 Ṣé òjíṣẹ́ Kristi ni wọ́n? Mo fèsì bí ayírí, mo jẹ́ òjíṣẹ́ Kristi lọ́nà tó ta wọ́n yọ: mo ti ṣiṣẹ́ jù wọ́n lọ,+ wọ́n ti jù mí sẹ́wọ̀n lọ́pọ̀ ìgbà,+ wọ́n ti lù mí láìmọye ìgbà, ọ̀pọ̀ ìgbà sì ni ẹ̀mí mi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́.+ 24 Ìgbà márùn-ún ni àwọn Júù nà mí ní ẹgba mọ́kàndínlógójì (39),+ 25 ìgbà mẹ́ta ni wọ́n ti fi ọ̀pá nà mí,+ wọ́n sọ mí lókùúta lẹ́ẹ̀kan,+ ìgbà mẹ́ta ni mo ti wọkọ̀ tó rì,+ mo sì ti lo ọ̀sán kan àti òru kan lórí agbami òkun; 26 nínú ìrìn àjò lọ́pọ̀ ìgbà, nínú ewu odò, nínú ewu dánàdánà, nínú ewu látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tèmi,+ nínú ewu látọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,+ nínú ewu láàárín ìlú,+ nínú ewu láàárín aginjù, nínú ewu lójú òkun, nínú ewu láàárín àwọn èké arákùnrin,

Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́