24 Nítorí ọkùnrin kan wà tó ń jẹ́ Dímẹ́tíríù, alágbẹ̀dẹ fàdákà tó ń fi fàdákà ṣe ojúbọ Átẹ́mísì, ó máa ń mú èrè púpọ̀ wọlé fún àwọn oníṣẹ́ ọnà.+ 25 Ó kó wọn jọ pẹ̀lú àwọn míì tó ń ṣe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ mọ̀ dáadáa pé òwò yìí ló mú ká láásìkí.