46 ó sì sọ fún wọn pé: “Ohun tí a kọ nìyí: pé Kristi máa jìyà, ó sì máa dìde láàárín àwọn òkú ní ọjọ́ kẹta,+ 47 àti pé ní gbogbo orílẹ̀-èdè,+ bẹ̀rẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù,+ a máa wàásù ní orúkọ rẹ̀ pé kí àwọn èèyàn ronú pìwà dà kí wọ́n lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.+