23 Ní òru yìí, áńgẹ́lì+ Ọlọ́run tí mo jẹ́ tirẹ̀, tí mo sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, 24 ó sì sọ pé: ‘Má bẹ̀rù, Pọ́ọ̀lù. Wàá dúró níwájú Késárì,+ sì wò ó! Ọlọ́run ti fún ọ ní gbogbo àwọn tí ẹ jọ wà nínú ọkọ̀.’
23 Wọ́n wá ṣètò ọjọ́ kan láti wá bá a, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ibi tó ń gbé, kódà àwọn tó wá pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ. Láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, ó ṣàlàyé ọ̀ràn náà fún wọn bí ó ṣe ń jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run, kó lè yí èrò tí wọ́n ní nípa Jésù pa dà+ nípasẹ̀ Òfin Mósè+ àti ìwé àwọn Wòlíì.+
30 Torí náà, ó lo odindi ọdún méjì ní ilé tí òun fúnra rẹ̀ gbà,+ ó sì máa ń gba gbogbo àwọn tó bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tọwọ́tẹsẹ̀, 31 ó ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run fún wọn, ó sì ń kọ́ wọn nípa Jésù Kristi Olúwa ní fàlàlà,*+ láìsí ìdíwọ́.