2 Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn èèyàn sàràkí-sàràkí lára àwọn Júù wá sọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù láìdáa lójú rẹ̀.+ Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Fẹ́sítọ́ọ̀sì 3 pé kó ṣojú rere sáwọn, kó ránṣẹ́ pe Pọ́ọ̀lù wá sí Jerúsálẹ́mù. Àmọ́ ṣe ni wọ́n ń gbèrò láti lúgọ de Pọ́ọ̀lù kí wọ́n sì pa á lójú ọ̀nà.+