16 “Torí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni,+ kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.+
4 Àmọ́ Ọlọ́run, tí àánú rẹ̀ pọ̀,+ nítorí ìfẹ́ ńlá tó ní sí wa,+5 sọ wá di ààyè pẹ̀lú Kristi, kódà nígbà tí a kú nínú àwọn àṣemáṣe wa,+ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ mú kí ẹ rí ìgbàlà.
18 Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀, Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún kú mọ́ láé,+ ó jẹ́ olódodo tó kú nítorí àwọn aláìṣòdodo,+ kó lè mú yín wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run.+ Wọ́n pa á nínú ẹran ara,+ àmọ́ a sọ ọ́ di ààyè nínú ẹ̀mí.+