38 “Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ jẹ́ kó yé yín pé ipasẹ̀ ẹni yìí la fi ń kéde ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín,+39 àti pé nínú gbogbo ohun tí a kò lè sọ pé ẹ ò jẹ̀bi rẹ̀ nípasẹ̀ Òfin Mósè,+ ni à ń tipasẹ̀ ẹni yìí pe gbogbo ẹni tó bá gbà gbọ́ ní aláìlẹ́bi.+
16 “‘Májẹ̀mú tí màá bá wọn dá lẹ́yìn ìgbà yẹn nìyí,’ ni Jèhófà* wí. ‘Màá fi àwọn òfin mi sínú ọkàn wọn, inú èrò wọn ni màá sì kọ ọ́ sí.’”+17 Ó wá sọ pé: “Mi ò sì ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́ àti àwọn ìwà wọn tí kò bófin mu.”+