-
1 Pétérù 4:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Bí kálukú bá ṣe ń rí ẹ̀bùn gbà, ẹ máa fi ṣe ìránṣẹ́ fún ara yín bí ìríjú àtàtà tó ń rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run gbà lóríṣiríṣi ọ̀nà.+ 11 Tí ẹnikẹ́ni bá ń sọ̀rọ̀, kó sọ ọ́ bíi pé ó ń kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; tí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe ìránṣẹ́, kó ṣe é bí ẹni tó gbára lé okun tí Ọlọ́run ń fúnni;+ ká lè yin Ọlọ́run lógo nínú ohun gbogbo+ nípasẹ̀ Jésù Kristi. Ògo àti agbára jẹ́ tirẹ̀ títí láé àti láéláé. Àmín.
-