11 Torí pé ìgbà gbogbo ni àwọn òtòṣì á máa wà ní ilẹ̀ rẹ.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi ń pàṣẹ fún ọ pé, ‘Kí o lawọ́ dáadáa sí arákùnrin rẹ tí ìyà ń jẹ tó sì tòṣì ní ilẹ̀ rẹ.’+
2 Nígbà tí àdánwò ńlá pọ́n wọn lójú, ayọ̀ tó gba ọkàn wọn bí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ òtòṣì paraku fi hàn pé wọ́n ní ọrọ̀ nípa tẹ̀mí, torí pé wọ́n lawọ́ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀.*