23 Ni Jèhófà Ọlọ́run bá lé e kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì + kó lè máa ro ilẹ̀ tí a ti mú un jáde.+ 24 Torí náà, ó lé ọkùnrin náà jáde, ó sì fi àwọn kérúbù+ àti idà oníná tó ń yí láìdáwọ́ dúró sí ìlà oòrùn ọgbà Édẹ́nì, kí wọ́n lè máa ṣọ́ ọ̀nà tó lọ síbi igi ìyè náà.