-
Róòmù 15:26, 27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Nítorí ó ti ń wu àwọn tó wà ní Makedóníà àti Ákáyà láti fi lára àwọn nǹkan wọn ṣe ìtìlẹ́yìn fún àwọn aláìní tó wà lára àwọn ẹni mímọ́ ní Jerúsálẹ́mù.+ 27 Lóòótọ́, ó wù wọ́n láti ṣe bẹ́ẹ̀, torí ní ti gidi, wọ́n jẹ wọ́n ní gbèsè; nítorí bí àwọn orílẹ̀-èdè bá ti pín nínú àwọn nǹkan tẹ̀mí wọn, àwọn náà jẹ wọ́n ní gbèsè láti fi àwọn nǹkan tara tí wọ́n ní ṣe ìtìlẹ́yìn fún wọn.+
-
-
Fílípì 4:15-17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Kódà, ẹ̀yin ará Fílípì náà mọ̀ pé lẹ́yìn tí ẹ kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere, nígbà tí mo kúrò ní Makedóníà, kò sí ìjọ kan tó bá mi dá sí ọ̀rọ̀ fífúnni àti gbígbà, àfi ẹ̀yin nìkan;+ 16 torí nígbà tí mo wà ní Tẹsalóníkà, ẹ fi nǹkan tí mo nílò ránṣẹ́ sí mi, kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan péré, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni. 17 Kì í ṣe pé mò ń wá ẹ̀bùn, ohun rere tó máa mú èrè púpọ̀ sí i wá fún yín ni mò ń wá.
-