27 Àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àti àwọn alákòóso wọn kò dá ẹni yìí mọ̀, àmọ́ nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ onídàájọ́, wọ́n mú àwọn ohun tí àwọn Wòlíì sọ ṣẹ,+ èyí tí à ń kà sókè ní gbogbo sábáàtì. 28 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò rí ìdí kankan tó fi jẹ̀bi ikú,+ wọ́n ní kí Pílátù jẹ́ kí wọ́n pa á.+