-
Éfésù 1:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Àmọ́ ẹ̀yin náà nírètí nínú rẹ̀ lẹ́yìn tí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́, ìyẹn ìhìn rere nípa ìgbàlà yín. Lẹ́yìn tí ẹ gbà á gbọ́, a fi ẹ̀mí mímọ́ tí a ṣèlérí gbé èdìdì lé yín+ nípasẹ̀ rẹ̀, 14 ẹ̀mí mímọ́ yìí jẹ́ àmì ìdánilójú* ogún tí à ń retí,+ kí àwọn èèyàn* Ọlọ́run lè rí ìtúsílẹ̀+ nípasẹ̀ ìràpadà,+ sí ìyìn àti ògo rẹ̀.
-