-
2 Kọ́ríńtì 11:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Àmọ́ ẹ̀rù ń bà mí pé lọ́nà kan ṣáá, bí ejò ṣe fi ẹ̀tàn fa ojú Éfà mọ́ra,+ a lè sọ ìrònú yín dìbàjẹ́, tí ẹ ó sì yà kúrò nínú òtítọ́ inú àti ìwà mímọ́* tó yẹ Kristi.+ 4 Torí ní báyìí, tí ẹnì kan bá wá, tó sì wàásù Jésù kan yàtọ̀ sí èyí tí a ti wàásù tàbí tí ẹ bá gba ẹ̀mí kan tó yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà tàbí tí ẹ gba ìhìn rere kan tó yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà,+ ẹ̀ ń gba onítọ̀hún láyè láìjanpata.
-
-
Gálátíà 5:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Ẹ ti ń sáré dáadáa tẹ́lẹ̀.+ Ta ló dí yín lọ́wọ́ kí ẹ má ṣègbọràn sí òtítọ́ mọ́?
-