-
1 Kọ́ríńtì 13:4-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Ìfẹ́+ máa ń ní sùúrù*+ àti inú rere.+ Ìfẹ́ kì í jowú,+ kì í fọ́nnu, kì í gbéra ga,+ 5 kì í hùwà tí kò bójú mu,*+ kì í wá ire tirẹ̀ nìkan,+ kì í tètè bínú.+ Kì í di èèyàn sínú.*+ 6 Kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo,+ àmọ́ ó máa ń yọ̀ lórí òtítọ́. 7 Ó máa ń mú ohun gbogbo mọ́ra,+ ó máa ń gba ohun gbogbo gbọ́,+ ó máa ń retí ohun gbogbo,+ ó máa ń fara da ohun gbogbo.+
-