4Nítorí náà, èmi, ẹlẹ́wọ̀n+ nínú Olúwa, pàrọwà fún yín láti máa rìn lọ́nà tó yẹ+ pípè tí a pè yín, 2 pẹ̀lú gbogbo ìrẹ̀lẹ̀*+ àti ìwà tútù, pẹ̀lú sùúrù,+ kí ẹ máa fara dà á fún ara yín nínú ìfẹ́,+
14 Lẹ́sẹ̀ kan náà, ẹ̀yin ará, à ń rọ̀ yín pé kí ẹ máa kìlọ̀ fún àwọn tó ń ṣe ségesège,*+ ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn tó sorí kọ́,* ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ẹ máa mú sùúrù fún gbogbo èèyàn.+