16Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù dé Déébè, ó sì dé Lísírà.+ Ọmọ ẹ̀yìn kan wà níbẹ̀ tó ń jẹ́ Tímótì,+ ọmọkùnrin obìnrin Júù kan tó jẹ́ onígbàgbọ́, àmọ́ Gíríìkì ni bàbá rẹ̀, 2 àwọn ará ní Lísírà àti Íkóníónì sì ròyìn rẹ̀ dáadáa.
19 Ní báyìí, mo ní ìrètí pé, tí Jésù Olúwa bá fẹ́, màá rán Tímótì+ sí yín láìpẹ́, kí ara mi lè yá gágá nígbà tí mo bá gbọ́ ìròyìn nípa yín. 20 Nítorí mi ò ní ẹlòmíì tó níwà bíi tirẹ̀ tó máa fi òótọ́ inú bójú tó ọ̀rọ̀ yín.