-
Jẹ́nẹ́sísì 14:18-20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Melikisédékì+ ọba Sálẹ́mù+ sì gbé búrẹ́dì àti wáìnì jáde wá; òun ni àlùfáà Ọlọ́run Gíga Jù Lọ.+
19 Lẹ́yìn náà, ó súre fún un, ó sì sọ pé:
“Kí Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé
Bù kún Ábúrámù;
20 Ìyìn yẹ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ,
Ẹni tó mú kí ọwọ́ rẹ tẹ àwọn tó ń ni ọ́ lára!”
Ábúrámù sì fún un ní ìdá mẹ́wàá gbogbo nǹkan.+
-