22 Lẹ́yìn èyí, Ọlọ́run tòótọ́ dán Ábúráhámù wò,+ ó ní: “Ábúráhámù!” Ó fèsì pé: “Èmi nìyí!” 2 Ó wá sọ pé: “Jọ̀ọ́, mú ọmọ rẹ, ọmọ rẹ kan ṣoṣo tí o nífẹ̀ẹ́ gidigidi,+ ìyẹn Ísákì,+ kí o sì lọ sí ilẹ̀ Moráyà,+ kí o fi rú ẹbọ sísun níbẹ̀ lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè tí màá fi hàn ọ́.”