-
Dáníẹ́lì 3:23-25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Àmọ́ àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí, Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, ṣubú sínú iná ìléru tó ń jó náà ní dídè.
24 Jìnnìjìnnì wá bo Ọba Nebukadinésárì, ó yára dìde, ó sì sọ fún àwọn ìjòyè rẹ̀ pé: “Ṣebí ọkùnrin mẹ́ta la dè, tí a sì jù sínú iná?” Wọ́n dá ọba lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, ọba.” 25 Ó sọ pé: “Ẹ wò ó! Ọkùnrin mẹ́rin ni mò ń rí tí wọ́n ń rìn fàlàlà ní àárín iná náà, ohunkóhun ò ṣe wọ́n, ẹni kẹrin sì rí bí ọmọ àwọn ọlọ́run.”
-