ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 15:7, 8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 “Tí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rẹ bá di aláìní láàárín rẹ nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú rẹ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ, o ò gbọ́dọ̀ mú kí ọkàn rẹ le tàbí kí o háwọ́ sí arákùnrin rẹ tó jẹ́ aláìní.+ 8 Ṣe ni kí o lawọ́ sí i,+ kí o sì rí i dájú pé o yá a ní* ohunkóhun tó bá nílò tàbí tó ń jẹ ẹ́ níyà.

  • Mátíù 25:35, 36
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 35 Torí ebi pa mí, ẹ sì fún mi ní oúnjẹ; òùngbẹ gbẹ mí, ẹ sì fún mi ní nǹkan mu. Mo jẹ́ àjèjì, ẹ sì gbà mí lálejò;+ 36 mo wà ní ìhòòhò,* ẹ sì fi aṣọ wọ̀ mí.+ Mo ṣàìsàn, ẹ sì tọ́jú mi. Mo wà lẹ́wọ̀n, ẹ sì wá wò mí.’+

  • Lúùkù 3:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Ó sọ fún wọn pé: “Kí ẹni tó ní aṣọ méjì* fún ẹni tí kò ní lára aṣọ rẹ̀, kí ẹni tó sì ní ohun tó máa jẹ ṣe ohun kan náà.”+

  • Róòmù 12:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Ẹ máa ṣàjọpín nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́ kí wọ́n lè rí ohun tí wọ́n nílò.+ Ẹ máa ṣe aájò àlejò.+

  • 1 Tímótì 5:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Àmọ́ tí opó èyíkéyìí bá ní àwọn ọmọ tàbí ọmọ ọmọ, kí wọ́n kọ́kọ́ fi ìfọkànsin Ọlọ́run hùwà nínú ilé tiwọn,+ kí wọ́n sì san àwọn ohun tó yẹ pa dà fún àwọn òbí wọn àti àwọn òbí wọn àgbà,+ torí inú Ọlọ́run dùn sí èyí.+

  • Jémíìsì 1:27
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 27 Ìjọsìn* tó mọ́, tí kò sì ní ẹ̀gbin lójú Ọlọ́run àti Baba wa nìyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ aláìlóbìí+ àti àwọn opó+ nínú ìpọ́njú wọn,+ ká sì máa pa ara wa mọ́ láìní àbààwọ́n nínú ayé.+

  • 1 Jòhánù 3:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá ní ohun ìní ayé yìí, tó sì rí i pé arákùnrin rẹ̀ ṣaláìní síbẹ̀ tí kò ṣàánú rẹ̀, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe wà nínú rẹ̀?+

Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́