Ẹ́sírà
5 Nígbà náà, wòlíì Hágáì+ àti wòlíì Sekaráyà+ ọmọ ọmọ Ídò+ sọ tẹ́lẹ̀ fún àwọn Júù tó wà ní Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù, ní orúkọ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tó ń darí wọn. 2 Ìgbà náà ni Serubábélì+ ọmọ Ṣéálítíẹ́lì àti Jéṣúà+ ọmọ Jèhósádákì bẹ̀rẹ̀ sí í tún ilé Ọlọ́run kọ́,+ èyí tó wà ní Jerúsálẹ́mù; àwọn wòlíì Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn, wọ́n sì ń tì wọ́n lẹ́yìn.+ 3 Ní àkókò yẹn, Táténáì gómìnà agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò* àti Ṣetari-bósénáì pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn wá bá wọn, wọ́n sì bi wọ́n pé: “Ta ló fún yín láṣẹ láti kọ́ ilé yìí, kí ẹ sì parí iṣẹ́* rẹ̀?” 4 Wọ́n wá béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Kí lorúkọ àwọn ọkùnrin tó ń kọ́ ilé yìí?” 5 Àmọ́, ojú Ọlọ́run ò kúrò lára* àwọn àgbààgbà Júù,+ wọn ò sì dá wọn dúró títí wọ́n fi kọ̀wé ránṣẹ́ sí Dáríúsì, tí òun náà sì fi ìwé àṣẹ ránṣẹ́ pa dà lórí ọ̀rọ̀ náà.
6 Ẹ̀dà lẹ́tà tí Táténáì gómìnà agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò àti Ṣetari-bósénáì pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, àwọn gómìnà kéékèèké ní agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò, fi ránṣẹ́ sí Ọba Dáríúsì nìyí; 7 wọ́n fi ránṣẹ́ sí i, ohun tí wọ́n kọ nìyí:
“Sí Ọba Dáríúsì:
“Kí àlàáfíà wà pẹ̀lú rẹ! 8 A fẹ́ kí ọba mọ̀ pé a lọ sí ìpínlẹ̀* Júdà, ní ilé Ọlọ́run títóbi, wọ́n ń fi àwọn òkúta ńlá tí wọ́n ń yí sí àyè wọn kọ́ ilé náà, wọ́n sì ń to àwọn ẹ̀là gẹdú sí àwọn ògiri. Àwọn èèyàn náà ń fi ìtara ṣe iṣẹ́ náà, ìsapá wọn sì ń mú kó tẹ̀ síwájú. 9 A béèrè lọ́wọ́ àwọn àgbààgbà wọn pé: ‘Ta ló fún yín láṣẹ láti kọ́ ilé yìí, kí ẹ sì parí iṣẹ́* rẹ̀?’+ 10 A tún béèrè orúkọ wọn lọ́wọ́ wọn ká lè sọ fún ọ, ká sì lè kọ orúkọ àwọn ọkùnrin tó jẹ́ olórí wọn.
11 “Èsì tí wọ́n fún wa nìyí: ‘Àwa ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, ilé tí wọ́n kọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn là ń tún kọ́, èyí tí ọba ńlá kan ní Ísírẹ́lì kọ́, tó sì parí rẹ̀.+ 12 Àmọ́, nítorí pé àwọn baba wa múnú bí Ọlọ́run ọ̀run,+ ó fi wọ́n lé ọwọ́ Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì, ará Kálídíà tó wó ilé yìí lulẹ̀,+ tó sì kó àwọn èèyàn ibẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì.+ 13 Ṣùgbọ́n ní ọdún kìíní Kírúsì ọba Bábílónì, Ọba Kírúsì pàṣẹ pé kí a tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́.+ 14 Bákan náà, látinú tẹ́ńpìlì Bábílónì, Ọba Kírúsì kó àwọn ohun èlò wúrà àti fàdákà ilé Ọlọ́run jáde, èyí tí Nebukadinésárì kó kúrò nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ sí tẹ́ńpìlì Bábílónì.+ Ọba Kírúsì kó wọn fún ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ṣẹṣibásà,*+ ẹni tí Kírúsì fi ṣe gómìnà.+ 15 Kírúsì sọ fún un pé: “Kó àwọn ohun èlò yìí. Lọ kó wọn sínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, kí ẹ sì tún ilé Ọlọ́run kọ́ sí ibi tó wà tẹ́lẹ̀.”+ 16 Nígbà tí Ṣẹṣibásà yìí dé, ó fi ìpìlẹ̀ ilé Ọlọ́run lélẹ̀,+ èyí tó wà ní Jerúsálẹ́mù; àtìgbà yẹn ni wọ́n sì ti ń kọ́ ilé náà títí di báyìí, àmọ́ wọn ò tíì parí rẹ̀.’+
17 “Ní báyìí, tó bá dáa lójú ọba, jẹ́ kí wọ́n yẹ inú ibi ìṣúra ọba wò ní Bábílónì, láti mọ̀ bóyá Ọba Kírúsì pàṣẹ pé kí wọ́n tún ilé Ọlọ́run yẹn kọ́ ní Jerúsálẹ́mù;+ kí ọba sì fi ìpinnu rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí ránṣẹ́ sí wa.”