Diutarónómì
22 “Tí o bá rí akọ màlúù tàbí àgùntàn arákùnrin rẹ tó ń sọ nù lọ, má mọ̀ọ́mọ̀ mójú kúrò.+ Rí i dájú pé o mú un pa dà wá fún arákùnrin rẹ. 2 Àmọ́ tí arákùnrin rẹ ò bá gbé nítòsí rẹ tàbí tí o ò mọ̀ ọ́n, kí o mú ẹran náà lọ sí ilé rẹ, kó sì wà lọ́dọ̀ rẹ títí arákùnrin rẹ á fi máa wá a. Kí o sì dá a pa dà fún un.+ 3 Ohun tí wàá ṣe nìyẹn tí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, aṣọ rẹ̀ àti ohunkóhun tó sọ nù lọ́wọ́ arákùnrin rẹ. O ò gbọ́dọ̀ mójú kúrò.
4 “Tí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí akọ màlúù arákùnrin rẹ tó ṣubú lójú ọ̀nà, má mọ̀ọ́mọ̀ mójú kúrò. Rí i dájú pé o bá a gbé ẹran náà dìde.+
5 “Obìnrin kò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin kò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ obìnrin. Torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ kórìíra ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀.
6 “Tí o bá ṣàdédé rí ìtẹ́ ẹyẹ kan lójú ọ̀nà, tí àwọn ọmọ rẹ̀ tàbí àwọn ẹyin rẹ̀ wà nínú ìtẹ́ náà, ì báà jẹ́ lórí igi tàbí lórí ilẹ̀, tí àwọn ọmọ náà wà lábẹ́ ìyá wọn tàbí tó sàba lórí àwọn ẹyin náà, o ò gbọ́dọ̀ mú ìyá náà pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀.+ 7 Rí i dájú pé o jẹ́ kí ìyá wọn lọ, àmọ́ o lè kó àwọn ọmọ rẹ̀ sọ́dọ̀. Ohun tí o máa ṣe nìyí kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí ẹ̀mí rẹ sì lè gùn.
8 “Tí o bá kọ́ ilé tuntun, kí o ṣe ìgbátí sí òrùlé rẹ,+ kí o má bàa mú kí ilé rẹ jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ torí pé ẹnì kan já bọ́ látorí rẹ̀.
9 “O ò gbọ́dọ̀ fún oríṣi irúgbìn méjì sínú ọgbà àjàrà rẹ.+ Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, gbogbo ohun tó bá hù látinú irúgbìn tí o fún, títí kan àwọn ohun tó tinú ọgbà àjàrà náà jáde máa di ti ibi mímọ́.
10 “O ò gbọ́dọ̀ fi akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ túlẹ̀ pa pọ̀.+
11 “O ò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ tí wọ́n fi irun àgùntàn àti ọ̀gbọ̀ hun pa pọ̀.+
12 “Kí o ṣe kókó wajawaja sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin aṣọ tí o bá wọ̀.+
13 “Tí ọkùnrin kan bá gbéyàwó, tó sì bá ìyàwó rẹ̀ lò pọ̀ àmọ́ tó wá kórìíra rẹ̀,* 14 tó sì fi ẹ̀sùn kàn án pé ó ti ṣe ìṣekúṣe, tó wá sọ ọ́ lórúkọ burúkú, tó ń sọ pé: ‘Mo ti fẹ́ obìnrin yìí, àmọ́ nígbà tí mo bá a lò pọ̀, mi ò rí ẹ̀rí tó fi hàn pé kò tíì ní ìbálòpọ̀ rí,’ 15 kí bàbá àti ìyá ọmọbìnrin náà mú ẹ̀rí wá fún àwọn àgbààgbà ní ẹnubodè ìlú náà láti fi hàn pé ọmọbìnrin náà ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí. 16 Kí bàbá ọmọbìnrin náà sọ fún àwọn àgbààgbà pé, ‘Mo fún ọkùnrin yìí ní ọmọ mi pé kó fi ṣe aya, àmọ́ ó kórìíra rẹ̀,* 17 ó sì ń fẹ̀sùn kàn án pé oníṣekúṣe ni, ó ń sọ pé: “Mi ò rí ẹ̀rí pé ọmọbìnrin rẹ ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí.” Ẹ̀rí ọ̀hún rèé o, pé ọmọbìnrin mi ò ní ìbálòpọ̀ rí.’ Kí wọ́n wá tẹ́ aṣọ náà síwájú àwọn àgbààgbà ìlú. 18 Kí àwọn àgbààgbà ìlú+ mú ọkùnrin náà, kí wọ́n sì bá a wí.+ 19 Kí wọ́n bu owó ìtanràn lé e, kó jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ṣékélì* fàdákà, kí wọ́n sì kó o fún bàbá ọmọ náà, torí pé ọkùnrin náà ba wúńdíá Ísírẹ́lì lórúkọ jẹ́,+ ìyàwó rẹ̀ ló ṣì máa jẹ́. Ọkùnrin náà ò gbọ́dọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ tó bá fi wà láàyè.
20 “Àmọ́ tó bá jẹ́ òótọ́ ni ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, tí kò sì sí ẹ̀rí pé ọmọbìnrin náà ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí, 21 kí wọ́n mú ọmọbìnrin náà wá sí ẹnu ọ̀nà ilé bàbá rẹ̀, kí àwọn ọkùnrin ìlú rẹ̀ sì sọ ọ́ ní òkúta pa, torí ó ti hùwà tó ń dójú tini+ ní Ísírẹ́lì bó ṣe ṣe ìṣekúṣe* ní ilé bàbá rẹ̀.+ Kí ẹ mú ohun tó burú kúrò láàárín yín.+
22 “Tí ẹ bá rí ọkùnrin kan tó bá obìnrin tó jẹ́ ìyàwó ẹlòmíì sùn, ṣe ni kí ẹ pa àwọn méjèèjì, ọkùnrin tó bá obìnrin náà sùn pẹ̀lú obìnrin yẹn.+ Kí ẹ mú ohun tó burú kúrò ní Ísírẹ́lì.
23 “Tí wúńdíá kan bá ti ní àfẹ́sọ́nà, tí ọkùnrin míì wá rí wúńdíá náà nínú ìlú, tó sì bá a sùn, 24 kí ẹ mú àwọn méjèèjì wá sí ẹnubodè ìlú yẹn, kí ẹ sì sọ wọ́n ní òkúta pa, kí ẹ pa obìnrin náà torí pé kò kígbe nínú ìlú, kí ẹ sì pa ọkùnrin náà torí pé ó dójú ti ìyàwó ẹnì kejì rẹ̀.+ Kí ẹ mú ohun tó burú kúrò láàárín yín.
25 “Àmọ́ tó bá jẹ́ inú oko ni ọkùnrin náà ká obìnrin tó ní àfẹ́sọ́nà yẹn mọ́, tí ọkùnrin náà sì fi agbára mú un, tó sì bá a sùn, ọkùnrin tó bá a sùn yẹn nìkan ni kí ẹ pa, 26 àmọ́ ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun fún obìnrin náà. Obìnrin náà kò dá ẹ̀ṣẹ̀ tó gba pé kí ẹ pa á. Ṣe ni ọ̀rọ̀ yìí dà bíi ti ọkùnrin kan tó lu ẹnì kejì rẹ̀, tó sì pa á.*+ 27 Torí pé inú oko ló ká obìnrin náà mọ́, obìnrin tó ti ní àfẹ́sọ́nà yẹn sì kígbe, àmọ́ kò sẹ́ni tó lè gbà á sílẹ̀.
28 “Tí ọkùnrin kan bá rí ọmọbìnrin kan tí kò tíì ní ìbálòpọ̀ rí, tí kò sì ní àfẹ́sọ́nà, tí ọkùnrin náà wá gbá a mú tó sì bá a sùn, tí ọ̀rọ̀ náà wá hàn síta,+ 29 kí ọkùnrin tó bá a sùn fún bàbá ọmọbìnrin náà ní àádọ́ta (50) ṣékélì fàdákà, obìnrin náà á sì di ìyàwó rẹ̀.+ Torí pé ọkùnrin náà ti dójú tì í, kò gbọ́dọ̀ kọ obìnrin náà sílẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ tó bá fi wà láàyè.
30 “Ọkùnrin kankan ò gbọ́dọ̀ gba ìyàwó bàbá rẹ̀, kó má bàa dójú ti bàbá rẹ̀.*+