Ẹ́sítà
1 Nígbà ayé Ahasuérúsì,* ìyẹn Ahasuérúsì tó ṣàkóso ìpínlẹ̀* mẹ́tàdínláàádóje+ (127) láti Íńdíà títí dé Etiópíà,* 2 lákòókò yẹn, Ọba Ahasuérúsì wà lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní Ṣúṣánì*+ ilé ńlá,* 3 ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó se àsè ńlá fún gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Àwọn ọmọ ogun Páṣíà+ àti Mídíà,+ àwọn èèyàn pàtàkì àti àwọn olórí ìpínlẹ̀* wà níwájú rẹ̀, 4 ó sì fi ọrọ̀ ìjọba rẹ̀ ológo àti ọlá ńlá àti ẹwà títóbi rẹ̀ hàn fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, ìyẹn ọgọ́sàn-án (180) ọjọ́. 5 Nígbà tí àwọn ọjọ́ náà parí, ọba se àsè ńlá ní ọjọ́ méje fún gbogbo àwọn tó wà ní Ṣúṣánì* ilé ńlá,* látorí ẹni ńlá dórí ẹni kékeré ní àgbàlá tó wà ní ọgbà ààfin ọba. 6 Wọ́n fi okùn aṣọ àtàtà ta aṣọ ọ̀gbọ̀ àti aṣọ olówùú múlọ́múlọ́ àti aṣọ aláwọ̀ búlúù; òwú aláwọ̀ pọ́pù tí wọ́n so mọ́ àwọn òrùka fàdákà ni wọ́n fi ta wọ́n mọ́ àwọn òpó tí wọ́n fi òkúta mábù ṣe. Àwọn àga tìmùtìmù wúrà àti fàdákà sì wà lórí ibi tí wọ́n fi òkúta pọ́fírì àti òkúta mábù pẹ̀lú péálì àti òkúta mábù dúdú tẹ́.
7 Ife* wúrà ni wọ́n fi ń gbé wáìnì fúnni; àwọn ife náà yàtọ̀ síra, wáìnì tí ọba pèsè sì pọ̀ gan-an bí ọlá ọba ṣe pọ̀ tó. 8 Òfin tí wọ́n tẹ̀ lé ni pé kí wọ́n má fi dandan lé* iye ọtí tí ẹnì kan máa mu, torí ọba ti sọ fún àwọn òṣìṣẹ́ tó wà ní ààfin rẹ̀ pé kí kálukú ṣe bó ṣe fẹ́.
9 Bákan náà, Fáṣítì Ayaba+ se àsè ńlá fún àwọn obìnrin ní ilé* Ọba Ahasuérúsì.
10 Ní ọjọ́ keje, nígbà tí wáìnì ń mú inú ọba dùn,* ó sọ fún Méhúmánì, Bísítà, Hábónà,+ Bígítà, Ábágítà, Sétárì àti Kákásì, àwọn òṣìṣẹ́ méje tó wà láàfin tí wọ́n jẹ́ ẹmẹ̀wà* Ọba Ahasuérúsì fúnra rẹ̀, 11 pé kí wọ́n lọ mú Fáṣítì Ayaba wá síwájú ọba pẹ̀lú ìwérí ayaba* lórí rẹ̀, láti fi ẹwà rẹ̀ han àwọn èèyàn àti àwọn ìjòyè, nítorí ó lẹ́wà gan-an. 12 Ṣùgbọ́n Fáṣítì Ayaba kọ̀, kò wá ní gbogbo ìgbà tí àwọn òṣìṣẹ́ ààfin wá jíṣẹ́ ọba fún un. Nítorí náà, inú bí ọba gidigidi, ó sì gbaná jẹ.
13 Ọba wá sọ fún àwọn ọlọgbọ́n èèyàn tó ní ìjìnlẹ̀ òye nípa ìlànà* (bí ọ̀rọ̀ ọba ṣe dé iwájú gbogbo àwọn tó mọ òfin àti ẹjọ́ dunjú nìyẹn, 14 àwọn tó sún mọ́ ọn jù lọ ni Káṣénà, Ṣétárì, Ádímátà, Táṣíṣì, Mérésì, Másénà àti Mémúkánì, àwọn ìjòyè méje+ láti Páṣíà àti Mídíà, tí wọ́n máa ń wá sọ́dọ̀ ọba, tí wọ́n sì wà ní ipò tó ga jù nínú ìjọba náà). 15 Ọba béèrè pé: “Gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe sọ, kí ni ká ṣe sí Fáṣítì Ayaba nítorí kò tẹ̀ lé àṣẹ tí Ọba Ahasuérúsì pa láti ẹnu àwọn òṣìṣẹ́ ààfin?”
16 Ni Mémúkánì bá fèsì níwájú ọba àti àwọn ìjòyè pé: “Kì í ṣe ọba nìkan ni Fáṣítì Ayaba ṣe ohun tí kò dáa sí,+ ó tún kan gbogbo àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn èèyàn ní gbogbo ìpínlẹ̀* Ọba Ahasuérúsì. 17 Nítorí gbogbo àwọn aya á gbọ́ ohun tí ayaba ṣe, wọn ò sì ní ka ọkọ wọn sí, wọ́n á máa sọ pé, ‘Ọba Ahasuérúsì sọ pé kí wọ́n mú Fáṣítì Ayaba wá síwájú òun, àmọ́ ó kọ̀, kò wá.’ 18 Lónìí yìí, àwọn ìyàwó ìjòyè Páṣíà àti Mídíà tí wọ́n gbọ́ ohun tí ayaba ṣe á máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ sí gbogbo àwọn ìjòyè ọba, èyí á sì yọrí sí ọ̀pọ̀ ẹ̀gàn àti ìbínú. 19 Tó bá dáa lójú ọba, kó pa àṣẹ kan, kí wọ́n sì kọ ọ́ sínú àwọn òfin Páṣíà àti Mídíà tí kò ṣeé yí pa dà,+ pé kí Fáṣítì má ṣe wá síwájú Ọba Ahasuérúsì mọ́ láé; kí ọba sì fi ipò ayaba fún obìnrin tó sàn jù ú lọ. 20 Nígbà tí wọ́n bá gbọ́ àṣẹ tí ọba pa ní gbogbo ilẹ̀ àkóso rẹ̀ tó fẹ̀, gbogbo àwọn aya á máa bọlá fún ọkọ wọn, látorí ẹni ńlá dórí ẹni kékeré.”
21 Àbá yìí dára lójú ọba àti àwọn ìjòyè, ọba sì ṣe ohun tí Mémúkánì sọ. 22 Nítorí náà, ó fi àwọn lẹ́tà ránṣẹ́ sí gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà lábẹ́ àṣẹ ọba,+ sí ìpínlẹ̀* kọ̀ọ̀kan ní ọ̀nà ìgbàkọ̀wé tirẹ̀ àti sí àwùjọ èèyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè tirẹ̀, pé kí ọkọ kọ̀ọ̀kan jẹ́ olórí* ní ilé rẹ̀, èdè àwọn èèyàn rẹ̀ ni kó sì máa sọ.