Jóṣúà
7 Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun tí kò tọ́ nípa ohun tí wọ́n máa pa run, torí Ákánì+ ọmọ Kámì, ọmọ Sábídì, ọmọ Síírà látinú ẹ̀yà Júdà kó lára àwọn ohun tí wọ́n máa pa run.+ Ìyẹn mú kí Jèhófà bínú gidigidi sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
2 Jóṣúà wá rán àwọn ọkùnrin jáde láti Jẹ́rìkò lọ sí Áì,+ tó wà nítòsí Bẹti-áfénì, ní ìlà oòrùn Bẹ́tẹ́lì,+ ó sọ fún wọn pé: “Ẹ gòkè lọ ṣe amí ilẹ̀ náà.” Àwọn ọkùnrin náà sì lọ ṣe amí ìlú Áì. 3 Nígbà tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ Jóṣúà, wọ́n sọ fún un pé: “Kò pọn dandan kí gbogbo èèyàn lọ. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) tàbí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin ti tó láti ṣẹ́gun ìlú Áì. Má ṣe jẹ́ kí gbogbo èèyàn lọ, kí o má bàa tán wọn lókun torí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀.”
4 Torí náà, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin lọ síbẹ̀, àmọ́ ṣe ni wọ́n sá fún àwọn ọkùnrin Áì.+ 5 Àwọn ọkùnrin Áì pa ọkùnrin mẹ́rìndínlógójì (36), wọ́n sì lé wọn láti ẹ̀yìn ẹnubodè ìlú títí dé Ṣébárímù,* wọ́n ń pa wọ́n ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè. Jìnnìjìnnì bá àwọn èèyàn náà, ọkàn* wọn sì domi.
6 Ni Jóṣúà bá fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wólẹ̀ níwájú Àpótí Jèhófà títí di ìrọ̀lẹ́, òun àti àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì, wọ́n sì ń da iyẹ̀pẹ̀ sí orí ara wọn. 7 Jóṣúà sọ pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, kí ló dé tí o mú àwọn èèyàn yìí wá láti ìsọdá Jọ́dánì lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún torí kí o kàn lè fi wá lé àwọn Ámórì lọ́wọ́, kí wọ́n sì pa wá dà nù? À bá ti jẹ́ kí òdìkejì* Jọ́dánì tẹ́ wa lọ́rùn, ká sì dúró síbẹ̀! 8 Jọ̀ọ́, Jèhófà, kí ni kí n sọ báyìí tí Ísírẹ́lì ti sá fún* àwọn ọ̀tá rẹ̀? 9 Tí àwọn ọmọ Kénáánì àti gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà bá gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n á yí wa ká, wọ́n á sì pa orúkọ wa rẹ́ kúrò ní ayé, kí lo máa wá ṣe nípa orúkọ ńlá rẹ?”+
10 Jèhófà dá Jóṣúà lóhùn pé: “Dìde! Kí ló dé tí o dojú bolẹ̀? 11 Ísírẹ́lì ti ṣẹ̀. Wọ́n ti da májẹ̀mú mi+ tí mo pa láṣẹ pé kí wọ́n pa mọ́. Wọ́n kó lára ohun tí wọ́n máa pa run,+ wọ́n jí i,+ wọ́n sì lọ kó o pa mọ́ sáàárín ohun ìní wọn.+ 12 Torí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ní lè dìde sí àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n á yí pa dà lẹ́yìn àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n á sì sá lọ, torí wọ́n ti di ohun tí a máa pa run. Mi ò ní wà pẹ̀lú yín mọ́, àfi tí ẹ bá run ohun tí a máa pa run tó wà láàárín yín.+ 13 Dìde, kí o sì sọ àwọn èèyàn náà di mímọ́!+ Sọ fún wọn pé, ‘Ẹ sọ ara yín di mímọ́ torí ọ̀la, nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ohun tí a máa pa run wà ní àárín yín. Ẹ ò ní lè dìde sí àwọn ọ̀tá yín títí ẹ fi máa mú ohun tí a máa pa run kúrò láàárín yín. 14 Tó bá di àárọ̀, kí ẹ wá ní ẹ̀yà-ẹ̀yà, ẹ̀yà tí Jèhófà bá sì mú máa wá ní ìdílé-ìdílé, ìdílé tí Jèhófà bá sì mú+ máa wá ní agboolé-agboolé, àwọn ọkùnrin ní agbo ilé tí Jèhófà bá sì mú máa wá lọ́kọ̀ọ̀kan. 15 Ẹni tí a bá rí ohun tí a máa pa run lọ́wọ́ rẹ̀, ṣe la máa dáná sun ún,+ òun àti gbogbo ohun tó jẹ́ tirẹ̀, torí pé ó ti da májẹ̀mú+ Jèhófà àti pé ó ti hùwà tó ń dójú tini ní Ísírẹ́lì.”’”
16 Jóṣúà wá dìde ní àárọ̀ kùtù ọjọ́ kejì, ó ní kí Ísírẹ́lì wá ní ẹ̀yà-ẹ̀yà, a sì mú ẹ̀yà Júdà. 17 Ó ní kí àwọn ìdílé Júdà wá, a sì mú ìdílé àwọn ọmọ Síírà,+ lẹ́yìn náà, ó ní kí àwọn ọkùnrin ní ìdílé àwọn ọmọ Síírà wá lọ́kọ̀ọ̀kan, a sì mú Sábídì. 18 Níkẹyìn, ó ní kí àwọn ọkùnrin ní agboolé Sábídí wá lọ́kọ̀ọ̀kan, a sì mú Ákánì ọmọ Kámì, ọmọ Sábídí, ọmọ Síírà látinú ẹ̀yà Júdà.+ 19 Jóṣúà wá sọ fún Ákánì pé: “Ọmọ mi, jọ̀ọ́, bọlá fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kí o sì jẹ́wọ́ fún un. Jọ̀ọ́, sọ ohun tí o ṣe fún mi. Má fi pa mọ́ fún mi.”
20 Ákánì dá Jóṣúà lóhùn pé: “Kí n sòótọ́, èmi ni mo ṣẹ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ohun tí mo sì ṣe nìyí. 21 Nígbà tí mo rí ẹ̀wù oyè kan tó rẹwà láti Ṣínárì+ láàárín àwọn ẹrù ogun àti igba (200) ṣékélì* fàdákà àti wúrà gbọọrọ kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta (50) ṣékélì, ọkàn mi fà sí i, mo sì kó o. Abẹ́ ilẹ̀ nínú àgọ́ mi ni mo kó o pa mọ́ sí, mo sì kó owó náà sábẹ́ rẹ̀.”
22 Ni Jóṣúà bá ní kí àwọn ìránṣẹ́ lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n sì sáré lọ sínú àgọ́ náà, wọ́n rí ẹ̀wù náà nínú àgọ́ rẹ̀ níbi tó tọ́jú rẹ̀ sí, wọ́n sì rí owó náà lábẹ́ rẹ̀. 23 Wọ́n wá kó àwọn nǹkan náà kúrò nínú àgọ́ náà, wọ́n kó o wá sọ́dọ̀ Jóṣúà àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì kó o síwájú Jèhófà. 24 Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì wá mú Ákánì+ ọmọ Síírà, fàdákà náà, ẹ̀wù oyè náà àti wúrà gbọọrọ náà,+ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, akọ màlúù rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, agbo ẹran rẹ̀, àgọ́ rẹ̀ àti gbogbo ohun tó jẹ́ tirẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá sí Àfonífojì* Ákórì.+ 25 Jóṣúà sọ pé: “Kí ló dé tí o fa àjálù* bá wa?+ Jèhófà máa mú àjálù bá ọ lónìí.” Ni gbogbo Ísírẹ́lì bá sọ ọ́ lókùúta,+ lẹ́yìn náà, wọ́n dáná sun wọ́n.+ Bí wọ́n ṣe sọ gbogbo wọn lókùúta nìyẹn. 26 Wọ́n kó òkúta jọ pelemọ lé e lórí, ó sì wà bẹ́ẹ̀ títí dòní. Bí inú tó ń bí Jèhófà gidigidi ṣe rọlẹ̀ nìyẹn.+ Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Àfonífojì Ákórì* títí dòní.