Àwọn Ọba Kìíní
5 Nígbà tí Hírámù ọba Tírè+ gbọ́ pé a ti fòróró yan Sólómọ́nì láti jọba ní ipò bàbá rẹ̀, ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí Sólómọ́nì, nítorí tipẹ́tipẹ́ ni Hírámù ti jẹ́ ọ̀rẹ́* Dáfídì.+ 2 Ni Sólómọ́nì bá ránṣẹ́ sí Hírámù+ pé: 3 “O mọ̀ dáadáa pé Dáfídì bàbá mi kò lè kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ nítorí ogun tí wọ́n fi yí i ká, títí Jèhófà fi fi àwọn ọ̀tá rẹ̀ sábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.+ 4 Àmọ́ ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run mi ti fún mi ní ìsinmi yí ká.+ Kò sí alátakò kankan, láburú kankan ò sì ṣẹlẹ̀.+ 5 Torí náà, mo fẹ́ kọ́ ilé kan fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run mi, bí Jèhófà ti ṣèlérí fún Dáfídì bàbá mi pé: ‘Ọmọ rẹ tí màá fi sórí ìtẹ́ rẹ láti rọ́pò rẹ ni ó máa kọ́ ilé fún orúkọ mi.’+ 6 Ní báyìí, sọ fún àwọn èèyàn rẹ pé kí wọ́n gé igi kédárì ti Lẹ́bánónì+ fún mi. Àwọn ìránṣẹ́ mi á bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ ṣiṣẹ́, màá san owó iṣẹ́ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, iye tí o bá sì sọ ni màá san, nítorí o mọ̀ pé kò sí ìkankan lára wa tó mọ bí a ṣe ń gé igi bí àwọn ọmọ Sídónì.”+
7 Nígbà tí Hírámù gbọ́ ohun tí Sólómọ́nì sọ, inú rẹ̀ dùn gan-an, ó sì sọ pé: “Ìyìn ni fún Jèhófà lónìí, nítorí ó ti fún Dáfídì ní ọlọ́gbọ́n ọmọ tó máa darí ọ̀pọ̀ èèyàn* yìí!”+ 8 Torí náà, Hírámù ránṣẹ́ sí Sólómọ́nì pé: “Mo ti gbọ́ iṣẹ́ tí o rán sí mi. Màá ṣe gbogbo ohun tí o fẹ́, màá fún ọ ní gẹdú igi kédárì àti igi júnípà.+ 9 Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò kó wọn wá láti Lẹ́bánónì sí òkun, màá dì wọ́n ní àdìpọ̀ igi gẹdú kí ó lè gba orí òkun lọ sí ibi tí o bá ní kí n kó wọn sí. Màá ní kí wọ́n la àwọn igi náà níbẹ̀, kí o lè kó wọn lọ. Oúnjẹ tí mo bá béèrè fún agbo ilé+ mi ni wàá fi san án pa dà fún mi.”
10 Nítorí náà, Hírámù fún Sólómọ́nì ní gbogbo gẹdú igi kédárì àti igi júnípà tó fẹ́. 11 Sólómọ́nì fún Hírámù ní ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀* àlìkámà* kó lè jẹ́ oúnjẹ fún agbo ilé rẹ̀ àti ogún (20) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀ ògidì òróró ólífì.* Ohun tí Sólómọ́nì máa ń fún Hírámù nìyẹn lọ́dọọdún.+ 12 Jèhófà fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n, bí ó ti ṣèlérí fún un.+ Àlàáfíà wà láàárín Hírámù àti Sólómọ́nì, àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn.*
13 Ọba Sólómọ́nì ní kí àwọn ọkùnrin kan láti gbogbo Ísírẹ́lì máa ṣiṣẹ́ fún òun;+ wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ (30,000) ọkùnrin. 14 Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) lára wọn ló máa ń rán lọ sí Lẹ́bánónì lóṣooṣù láti gba iṣẹ́ lọ́wọ́ ara wọn. Wọ́n á lo oṣù kan ní Lẹ́bánónì, wọ́n á sì lo oṣù méjì ní ilé wọn; Ádónírámù+ sì ni olórí àwọn tí ọba ní kó máa ṣiṣẹ́ fún òun. 15 Sólómọ́nì ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ (70,000) lébìrà* àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) àwọn tó ń gé òkúta+ ní àwọn òkè+ 16 àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (3,300) ìjòyè+ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ àbójútó láti máa darí àwọn òṣìṣẹ́. 17 Ọba pàṣẹ pé kí wọ́n fọ́ àwọn òkúta ńláńlá, àwọn òkúta iyebíye,+ kí wọ́n lè fi òkúta tí wọ́n bá gbẹ́+ ṣe ìpìlẹ̀ ilé+ náà. 18 Torí náà, àwọn kọ́lékọ́lé Sólómọ́nì àti ti Hírámù pẹ̀lú àwọn ará Gébálì+ gé àwọn òkúta náà, wọ́n sì ṣètò àwọn gẹdú àti àwọn òkúta tí wọ́n máa fi kọ́ ilé náà.