Nehemáyà
5 Àwọn èèyàn náà àti àwọn ìyàwó wọn gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì ń sunkún nítorí ohun tí àwọn Júù, arákùnrin wọn ń ṣe.+ 2 Àwọn kan ń sọ pé: “Àwa àti àwọn ọmọkùnrin wa pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin wa pọ̀. A gbọ́dọ̀ rí oúnjẹ* tí a máa jẹ, kí a má bàa kú.” 3 Àwọn míì ń sọ pé: “Àwọn oko wa àti àwọn ọgbà àjàrà wa pẹ̀lú àwọn ilé wa la fi ṣe ohun ìdúró, ká lè rí ọkà lásìkò tí kò sí oúnjẹ.” 4 Àwọn míì sì tún ń sọ pé: “A ti fi àwọn oko wa àti àwọn ọgbà àjàrà wa yá owó ká lè rí ìṣákọ́lẹ̀* ọba san.+ 5 Ara kan náà àti ẹ̀jẹ̀ kan náà ni àwa àti àwọn arákùnrin wa,* bí àwọn ọmọ wọn ṣe rí náà ni àwọn ọmọ wa rí; síbẹ̀ a ní láti sọ àwọn ọmọkùnrin wa àti àwọn ọmọbìnrin wa di ẹrú, kódà lára àwọn ọmọbìnrin wa ti di ẹrú.+ Àmọ́, a ò ní agbára kankan láti dá èyí dúró, nítorí àwọn oko wa àti àwọn ọgbà àjàrà wa ti di ti àwọn ẹlòmíì.”
6 Inú bí mi gan-an nígbà tí mo gbọ́ igbe ẹkún wọn àti ọ̀rọ̀ yìí. 7 Nítorí náà, mo ro gbogbo rẹ̀ lọ́kàn mi, mo sì bá àwọn èèyàn pàtàkì àti àwọn alábòójútó wí, mo sọ fún wọn pé: “Kálukú yín ń gba èlé* lọ́wọ́ arákùnrin rẹ̀.”+
Yàtọ̀ síyẹn, mo ṣètò àpéjọ ńlá kan nítorí wọn. 8 Mo sọ fún wọn pé: “A ti ra àwọn Júù arákùnrin wa tí wọ́n tà fún àwọn orílẹ̀-èdè pa dà débi tí agbára wa gbé e dé; àmọ́, ṣé ẹ máa wá ta àwọn arákùnrin yín ni,+ ṣé ó yẹ ká tún rà wọ́n pa dà lọ́wọ́ yín ni?” Ni kẹ́kẹ́ bá pa mọ́ wọn lẹ́nu, wọn ò sì rí nǹkan kan sọ. 9 Lẹ́yìn náà, mo sọ pé: “Ohun tí ẹ̀ ń ṣe yìí kò dára. Ṣé kò yẹ kí ẹ máa rìn nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run wa+ kí àwọn orílẹ̀-èdè, ìyẹn àwọn ọ̀tá wa má bàa pẹ̀gàn wa ni? 10 Yàtọ̀ síyẹn, èmi àti àwọn arákùnrin mi pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ mi ń yá wọn ní owó àti ọkà. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ jẹ́ ká jáwọ́ nínú gbígba èlé lórí ohun tí a yáni.+ 11 Ẹ jọ̀ọ́, ẹ dá àwọn nǹkan tí ẹ ti gbà pa dà fún wọn lónìí,+ ìyẹn ilẹ̀ wọn, ọgbà àjàrà wọn, oko ólífì wọn àti ilé wọn, títí kan ìdá ọgọ́rùn-ún* owó, ọkà, wáìnì tuntun àti òróró tí ẹ̀ ń gbà lọ́wọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí èlé.”
12 Wọ́n wá fèsì pé: “A máa dá nǹkan wọ̀nyí pa dà fún wọn, a ò sì ní béèrè ohunkóhun pa dà. A máa ṣe ohun tí o sọ.” Torí náà, mo pe àwọn àlùfáà, mo sì mú kí wọ́n búra pé wọ́n á mú ìlérí yìí ṣẹ. 13 Mo tún gbọn ibi tó ṣẹ́ po lára aṣọ* mi jáde, mo sì sọ pé: “Ní ọ̀nà yìí, kí Ọlọ́run tòótọ́ gbọn gbogbo ẹni tí kò bá mú ìlérí yìí ṣẹ kúrò nínú ilé rẹ̀ àti kúrò nínú ohun ìní rẹ̀, ọ̀nà yìí sì ni kí a gbà gbọ̀n ọ́n dà nù kí ó sì di òfo.” Gbogbo ìjọ fèsì pé: “Àmín!”* Wọ́n yin Jèhófà, àwọn èèyàn náà sì ṣe ohun tí wọ́n ṣèlérí.
14 Bákan náà, láti ọjọ́ tí ọba ti yàn mí láti di gómìnà wọn+ ní ilẹ̀ Júdà, láti ogún ọdún+ sí ọdún kejìlélọ́gbọ̀n+ Ọba Atasásítà,+ ó jẹ́ ọdún méjìlá (12), èmi àti àwọn arákùnrin mi kò jẹ oúnjẹ tó yẹ gómìnà.+ 15 Àmọ́, àwọn gómìnà tó wà ṣáájú mi ti di ẹrù tó wúwo sórí àwọn èèyàn náà, wọ́n sì ń gba ogójì (40) ṣékélì* fàdákà lọ́wọ́ wọn fún oúnjẹ àti wáìnì lójoojúmọ́. Àwọn ìránṣẹ́ wọn tún ń ni àwọn èèyàn lára. Ṣùgbọ́n mi ò ṣe bẹ́ẹ̀+ nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run.+
16 Yàtọ̀ síyẹn, mo ṣe nínú iṣẹ́ ògiri yìí, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi kóra jọ síbẹ̀ fún iṣẹ́ náà, a kò sì gba ilẹ̀ kankan.+ 17 Àádọ́jọ (150) Júù àti àwọn alábòójútó ló ń jẹun lórí tábìlì mi, títí kan àwọn tó wá sọ́dọ̀ wa látinú àwọn orílẹ̀-èdè. 18 Lójoojúmọ́, akọ màlúù kan, àgùntàn mẹ́fà tó dáa àti àwọn ẹyẹ* ni wọ́n ń pa fún mi,* a sì máa ń pèsè ọ̀pọ̀ wáìnì lóríṣiríṣi lẹ́ẹ̀kan lọ́jọ́ mẹ́wàá. Síbẹ̀, mi ò béèrè oúnjẹ tó yẹ gómìnà, nítorí pé iṣẹ́ tó wà lọ́rùn àwọn èèyàn náà pọ̀, ó sì ti wọ̀ wọ́n lọ́rùn. 19 Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́ rántí mi sí rere* lórí gbogbo ohun tí mo ti ṣe nítorí àwọn èèyàn yìí.+