Jóṣúà
9 Nígbà tí gbogbo àwọn ọba tó wà lápá ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì+ gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, àwọn tó wà ní agbègbè olókè, ní Ṣẹ́fẹ́là, ní gbogbo etí Òkun Ńlá*+ àti níwájú Lẹ́bánónì, ìyẹn àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àtàwọn ará Jébúsì,+ 2 wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti bá Jóṣúà àti Ísírẹ́lì jà.+
3 Àwọn tó ń gbé Gíbíónì+ náà gbọ́ ohun tí Jóṣúà ṣe sí Jẹ́ríkò+ àti Áì.+ 4 Torí náà, wọ́n dá ọgbọ́n kan, wọ́n kó oúnjẹ sínú àwọn àpò tó ti gbó, wọ́n sì gbé e sórí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, pẹ̀lú awọ tí wọ́n ń rọ wáìnì sí, tó ti gbó, tó sì ti bẹ́, àmọ́ tí wọ́n ti rán; 5 wọ́n tún wọ bàtà tó ti gbó, tí wọ́n sì ti lẹ̀, aṣọ ọrùn wọn náà ti gbó. Gbogbo búrẹ́dì tí wọ́n gbé dání ti gbẹ, ó sì ti ń rún. 6 Wọ́n wá lọ bá Jóṣúà níbi tí Ísírẹ́lì pàgọ́ sí ní Gílígálì,+ wọ́n sì sọ fún òun àtàwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì pé: “Ọ̀nà jíjìn la ti wá. Ẹ wá bá wa dá májẹ̀mú.” 7 Àmọ́ àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sọ fún àwọn Hífì+ pé: “Bóyá tòsí wa lẹ tiẹ̀ ń gbé. Báwo la ṣe máa bá yín dá májẹ̀mú?”+ 8 Wọ́n dá Jóṣúà lóhùn pé: “Ìránṣẹ́* rẹ ni wá.”
Jóṣúà wá bi wọ́n pé: “Ta ni yín, ibo lẹ sì ti wá?” 9 Wọ́n fèsì pé: Ọ̀nà tó jìn gan-an ni àwa ìránṣẹ́ rẹ ti wá,+ torí a gbọ́ nípa orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, òkìkí rẹ̀ kàn dé ọ̀dọ̀ wa, a sì ti gbọ́ nípa gbogbo ohun tó ṣe ní Íjíbítì+ 10 àti gbogbo ohun tó ṣe sí àwọn ọba Ámórì méjèèjì tí wọ́n wà ní òdìkejì* Jọ́dánì, ìyẹn Síhónì+ ọba Hẹ́ṣíbónì àti Ógù+ ọba Báṣánì, tó wà ní Áṣítárótì. 11 Torí náà, àwọn àgbààgbà wa àti gbogbo àwọn tó ń gbé ní ilẹ̀ wa sọ fún wa pé, ‘Ẹ kó oúnjẹ tí ẹ máa jẹ lẹ́nu ìrìn àjò yín dání, kí ẹ sì lọ bá wọn. Kí ẹ sọ fún wọn pé: “A máa di ìránṣẹ́ yín;+ kí ẹ bá wa dá májẹ̀mú.”’+ 12 Búrẹ́dì tí a kó dání yìí ṣì gbóná lọ́jọ́ tí a kúrò ní ilé wa láti wá bá yín níbí. Ẹ̀yin náà ẹ wò ó, ó ti gbẹ, ó sì ti ń rún.+ 13 Àwọn awọ yìí ṣì tuntun nígbà tí a rọ wáìnì sínú wọn, àmọ́ wọ́n ti bẹ́ báyìí.+ Aṣọ àti bàtà wa sì ti gbó torí pé ọ̀nà tí a rìn jìn gan-an.”
14 Ni àwọn ọkùnrin náà bá gbà lára oúnjẹ wọn,* àmọ́ wọn ò wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà.+ 15 Jóṣúà bá wọn ṣàdéhùn àlàáfíà,+ ó sì bá wọn dá májẹ̀mú pé òun máa dá ẹ̀mí wọn sí, ohun tí àwọn ìjòyè àpéjọ náà sì búra fún wọn nìyẹn.+
16 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n bá wọn dá májẹ̀mú, wọ́n gbọ́ pé tòsí wọn ni wọ́n ń gbé, ọ̀nà wọn ò sì jìn rárá. 17 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá gbéra, wọ́n sì dé àwọn ìlú wọn ní ọjọ́ kẹta; àwọn ìlú wọn ni Gíbíónì,+ Kéfírà, Béérótì àti Kiriati-jéárímù.+ 18 Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbéjà kò wọ́n, torí pé àwọn ìjòyè àpéjọ náà ti fi Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì búra+ fún wọn. Gbogbo àpéjọ náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí àwọn ìjòyè náà. 19 Ni gbogbo àwọn ìjòyè náà bá sọ fún gbogbo àpéjọ náà pé: “A ò lè pa wọ́n lára torí pé a ti fi Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì búra fún wọn. 20 Ohun tí a máa ṣe nìyí: A máa dá ẹ̀mí wọn sí, kí ìbínú má bàa wá sórí wa torí ìbúra tí a ṣe fún wọn.”+ 21 Àwọn ìjòyè náà sì sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká dá ẹ̀mí wọn sí, àmọ́ kí wọ́n máa bá wa ṣẹ́gi, kí wọ́n sì máa pọnmi fún gbogbo àpéjọ náà.” Ìlérí tí àwọn ìjòyè náà ṣe fún wọn nìyẹn.
22 Lẹ́yìn náà, Jóṣúà pè wọ́n, ó sì sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ tàn wá, tí ẹ sọ pé, ‘Ibi tó jìnnà gan-an sí yín la ti wá,’ nígbà tó jẹ́ pé àárín wa níbí lẹ̀ ń gbé?+ 23 Ẹni ègún ni yín látòní lọ,+ ẹrú ni ẹ ó sì máa jẹ́, ẹ̀ẹ́ máa ṣẹ́gi, ẹ̀ẹ́ sì máa pọnmi fún ilé Ọlọ́run mi.” 24 Wọ́n dá Jóṣúà lóhùn pé: “Torí àwa ìránṣẹ́ rẹ gbọ́ ọ kedere pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti pàṣẹ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀ láti fún yín ní gbogbo ilẹ̀ náà, pé òun máa pa gbogbo àwọn tó ń gbé ibẹ̀ run kúrò níwájú yín.+ Ìyẹn ló mú kí ẹ̀rù yín bà wá,+ torí a ò fẹ́ kí ẹ̀mí* wa lọ sí i la fi ṣe bẹ́ẹ̀.+ 25 Àfi kí o ṣàánú wa báyìí.* Ohunkóhun tí o bá rò pé ó tọ́, tó sì dáa ni kí o ṣe fún wa.” 26 Ohun tó sì ṣe sí wọn nìyẹn; ó gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọn ò sì pa wọ́n. 27 Àmọ́ ọjọ́ yẹn ni Jóṣúà sọ wọ́n di aṣẹ́gi àti àwọn tí á máa pọnmi fún àpéjọ náà+ àti pẹpẹ Jèhófà ní ibi tí Ó bá yàn,+ iṣẹ́ tí wọ́n sì ń ṣe títí di òní nìyẹn.+