Jóòbù
27 Jóòbù ń bá ọ̀rọ̀* rẹ̀ lọ, ó ní:
2 “Bó ṣe dájú pé Ọlọ́run wà láàyè, ẹni tó fi ìdájọ́ òdodo dù mí+
Àti bí Olódùmarè ti wà, ẹni tó mú kí n banú jẹ́,*+
3 Tí èémí mi bá ṣì wà nínú mi,
Tí ẹ̀mí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run sì wà nínú ihò imú mi,+
4 Ètè mi ò ní sọ̀rọ̀ àìṣòdodo;
Ahọ́n mi ò sì ní sọ* ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn!
5 Kò ṣeé gbọ́ pé kí n pe ẹ̀yin ọkùnrin yìí ní olódodo!
Títí màá fi kú, mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀!*+
7 Kó rí fún ọ̀tá mi bí ẹni burúkú,
Àwọn tó ń gbógun tì mí, bí aláìṣòdodo.
9 Ṣé Ọlọ́run máa gbọ́ igbe rẹ̀,
Tí wàhálà bá dé bá a?+
10 Àbí inú rẹ̀ á máa dùn nínú Olódùmarè?
Ṣé á máa ké pe Ọlọ́run nígbà gbogbo?
11 Màá kọ́ yín nípa agbára* Ọlọ́run;
Mi ò ní fi nǹkan kan pa mọ́ nípa Olódùmarè.
12 Ẹ wò ó! Tó bá jẹ́ pé gbogbo yín ti rí ìran,
Kí ló dé tí ọ̀rọ̀ yín kò nítumọ̀ rárá?
13 Èyí ni ìpín èèyàn burúkú látọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+
Ogún tí àwọn oníwà ìkà gbà látọ̀dọ̀ Olódùmarè.
14 Tí àwọn ọmọ rẹ̀ bá pọ̀, wọ́n á fi idà pa wọ́n,+
Àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ò sì ní ní oúnjẹ tó máa tó wọn.
15 Àjàkálẹ̀ àrùn ló máa sin àwọn tó bá gbẹ̀yìn rẹ̀,
Àwọn opó wọn ò sì ní sunkún nítorí wọn.
16 Tó bá tiẹ̀ to fàdákà jọ pelemọ bí erùpẹ̀,
Tó sì kó aṣọ olówó ńlá jọ bí amọ̀,
17 Bó tiẹ̀ kó o jọ,
Olódodo ló máa wọ̀ ọ́,+
Aláìṣẹ̀ sì máa pín fàdákà rẹ̀.
19 Ó máa lọ́rọ̀ nígbà tó bá dùbúlẹ̀, àmọ́ kò ní kó nǹkan kan jọ;
Nígbà tó bá la ojú rẹ̀, kò ní sí nǹkan kan níbẹ̀.
20 Ìbẹ̀rù bò ó bí àkúnya omi;
Ìjì gbé e lọ ní òru.+
21 Atẹ́gùn ìlà oòrùn máa gbé e lọ, kò sì ní sí mọ́;
Ó gbá a lọ kúrò ní àyè rẹ̀.+