Àìsáyà
Jókòó sílẹ̀ níbi tí kò sí ìtẹ́,+
Ìwọ ọmọbìnrin àwọn ará Kálídíà,
Torí àwọn èèyàn ò tún ní pè ọ́ ní ẹlẹgẹ́ àti àkẹ́jù mọ́.
2 Mú ọlọ, kí o sì lọ ìyẹ̀fun.
Yọ ìbòjú rẹ.
Bọ́ aṣọ rẹ, ká aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ.
Sọdá àwọn odò.
3 A máa tú ọ sí ìhòòhò.
Ìtìjú rẹ máa hàn síta.
Màá gbẹ̀san, + èèyàn kankan ò sì ní dá mi dúró.*
6 Inú bí mi sí àwọn èèyàn mi.+
Àmọ́ o ò ṣàánú wọn rárá.+
Kódà, o gbé àjàgà tó wúwo lé àgbàlagbà.+
7 O sọ pé: “Títí láé ni màá jẹ́ Ìyálóde.”*+
O ò fi àwọn nǹkan yìí sọ́kàn;
O ò ro ibi tí ọ̀rọ̀ náà máa já sí.
“Èmi ni ẹni náà, kò sí ẹlòmíì.+
Mi ò ní di opó.
Mi ò ní ṣòfò ọmọ láé.”+
9 Àmọ́ nǹkan méjèèjì yìí máa dé bá ọ lójijì, lọ́jọ́ kan ṣoṣo:+
Wàá ṣòfò ọmọ, wàá sì di opó.
10 O gbẹ́kẹ̀ lé ìwà burúkú rẹ.
O sọ pé: “Kò sẹ́ni tó ń rí mi.”
Ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ ló kó ọ ṣìnà,
O sì ń sọ lọ́kàn rẹ pé: “Èmi ni ẹni náà, kò sí ẹlòmíì.”
O máa ko àgbákò; o ò ní lè yẹ̀ ẹ́.
Ìparun òjijì máa dé bá ọ, irú èyí tí kò ṣẹlẹ̀ sí ọ rí.+
12 Máa fi èèdì di àwọn èèyàn lọ, kí o sì máa ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àjẹ́ rẹ,+
Èyí tí o ti ń ṣe kára látìgbà ọ̀dọ́ rẹ.
Bóyá wàá lè jàǹfààní;
Bóyá wàá lè mú kí ẹ̀rù ba àwọn èèyàn.
13 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ ti tán ọ lókun.
Kí wọ́n dìde báyìí, kí wọ́n sì gbà ọ́ là,
Àwọn tó ń jọ́sìn ọ̀run,* tí wọ́n ń wo ìràwọ̀,+
Àwọn tó ń fúnni ní ìmọ̀ nígbà òṣùpá tuntun,
Nípa àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ọ.
14 Wò ó! Wọ́n dà bí àgékù pòròpórò.
Iná máa jó wọn run.
Wọn ò lè gba ara* wọn lọ́wọ́ agbára ọwọ́ iná.
Àwọn èédú yìí kì í ṣe èyí tí a lè fi yáná,
Iná yìí kì í sì í ṣe èyí tí a lè jókòó síwájú rẹ̀.
15 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn atujú rẹ máa rí sí ọ,
Àwọn tí ẹ jọ ṣiṣẹ́ kára látìgbà ọ̀dọ́ rẹ.
Wọ́n máa rìn gbéregbère, kálukú ní ọ̀nà tirẹ̀.*
Kò ní sí ẹni tó máa gbà ọ́ là.+