Sí Àwọn Hébérù
8 Kókó ọ̀rọ̀ tí à ń sọ nìyí: A ní irú àlùfáà àgbà yìí,+ ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọba Ọlọ́lá ní ọ̀run,+ 2 òjíṣẹ́* ibi mímọ́+ àti àgọ́ tòótọ́, tí Jèhófà* gbé kalẹ̀, kì í ṣe èèyàn. 3 Torí gbogbo àlùfáà àgbà la yàn láti máa fi àwọn ọrẹ àti ẹbọ rúbọ; torí náà, ó pọn dandan fún ẹni yìí náà pé kó ní ohun kan láti fi rúbọ.+ 4 Tó bá jẹ́ pé ayé ló wà, kò ní jẹ́ àlùfáà,+ torí àwọn èèyàn tó ń fi ọrẹ rúbọ bí Òfin ṣe sọ ti wà. 5 Àwọn èèyàn yìí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ bí àpẹẹrẹ àti òjìji+ àwọn nǹkan ti ọ̀run;+ bí a ṣe pàṣẹ fún Mósè láti ọ̀run, nígbà tó fẹ́ kọ́ àgọ́ náà pé: Torí Ó sọ pé: “Rí i pé o ṣe gbogbo nǹkan bí ohun tí mo fi hàn ọ́ lórí òkè.”+ 6 Àmọ́ ní báyìí, Jésù ti gba iṣẹ́ òjíṣẹ́* tó lọ́lá jùyẹn lọ torí òun tún ni alárinà+ májẹ̀mú tó dáa jù,+ tó sì bá a mu rẹ́gí, èyí tí a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin lórí àwọn ìlérí tó dáa jù.+
7 Ká sọ pé májẹ̀mú àkọ́kọ́ yẹn ò ní àléébù ni, a ò ní nílò ìkejì.+ 8 Torí ó ń rí àléébù lára àwọn èèyàn nígbà tó sọ pé: “‘Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,’ ni Jèhófà* wí, ‘tí màá bá ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà dá májẹ̀mú tuntun. 9 Kò ní dà bíi májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá ní ọjọ́ tí mo dì wọ́n lọ́wọ́ mú láti mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ torí pé wọn ò pa májẹ̀mú mi mọ́, ìdí nìyẹn tí mi ò fi bójú tó wọn mọ́,’ ni Jèhófà* wí.
10 “‘Nítorí májẹ̀mú tí màá bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ìgbà yẹn nìyí,’ ni Jèhófà* wí. ‘Màá fi àwọn òfin mi sínú èrò wọn, inú ọkàn wọn sì ni màá kọ ọ́ sí.+ Màá di Ọlọ́run wọn, wọ́n á sì di èèyàn mi.+
11 “‘Kálukú wọn kò tún ní máa kọ́ ọmọ ìbílẹ̀ rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀ mọ́ pé: “Ẹ mọ Jèhófà!”* Nítorí gbogbo wọn á mọ̀ mí, látorí ẹni tó kéré jù lọ dórí ẹni tó tóbi jù lọ láàárín wọn. 12 Torí màá ṣàánú wọn lórí ọ̀rọ̀ ìwà àìṣòdodo wọn, mi ò sì ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.’”+
13 Bó ṣe pè é ní “májẹ̀mú tuntun,” ó ti sọ èyí tó wà tẹ́lẹ̀ di èyí tí kò wúlò mọ́.+ Ní báyìí, èyí tí kò wúlò mọ́, tó sì ti ń gbó lọ máa tó pa rẹ́ pátápátá.+