Àwọn Onídàájọ́
14 Sámúsìn sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Tímúnà, ó sì rí obìnrin Filísínì* kan ní Tímúnà. 2 Ó wá lọ sọ fún bàbá àti ìyá rẹ̀ pé: “Mo rí obìnrin Filísínì kan ní Tímúnà, mo sì fẹ́ kí ẹ fẹ́ ẹ fún mi kí n fi ṣe aya.” 3 Àmọ́, bàbá àti ìyá rẹ̀ sọ fún un pé: “Ṣé o ò rí obìnrin kankan láàárín àwọn mòlẹ́bí rẹ àti gbogbo àwọn èèyàn wa ni?+ Ṣé àárín àwọn Filísínì aláìdádọ̀dọ́* ló yẹ kí o ti lọ fẹ́ ìyàwó?” Àmọ́ Sámúsìn sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Òun ni kí o fẹ́ fún mi, torí òun lẹni tó yẹ mí.”* 4 Bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ ò mọ̀ pé Jèhófà ló fẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀, torí Ó ti ń ro bó ṣe máa gbógun ja àwọn Filísínì, torí pé àwọn Filísínì ń jọba lé Ísírẹ́lì lórí nígbà yẹn.+
5 Sámúsìn pẹ̀lú bàbá àti ìyá rẹ̀ wá sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Tímúnà. Nígbà tó dé àwọn ọgbà àjàrà Tímúnà, wò ó! kìnnìún* kan ń ké ramúramù bọ̀ wá bá a. 6 Àmọ́ ẹ̀mí Jèhófà fún un lágbára,+ ó sì fà á ya sí méjì, bí èèyàn ṣe ń fi ọwọ́ lásán fa ọmọ ewúrẹ́ ya sí méjì. Àmọ́ kò sọ ohun tó ṣe fún bàbá àti ìyá rẹ̀. 7 Ó wá lọ bá obìnrin náà sọ̀rọ̀, òun ló ṣì tọ́ lójú Sámúsìn.+
8 Lẹ́yìn náà, nígbà tó ń pa dà lọ kó lè mú obìnrin náà wá sílé,+ ó yà wo òkú kìnnìún náà, ó sì rí oyin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ kòkòrò oyin nínú òkú kìnnìún náà. 9 Ó wá fá oyin náà sọ́wọ́, ó sì ń lá a bó ṣe ń rìn lọ. Nígbà tó pa dà lọ bá bàbá àti ìyá rẹ̀, ó fún wọn jẹ lára rẹ̀. Àmọ́ kò sọ fún wọn pé inú òkú kìnnìún ni òun ti fá oyin náà.
10 Bàbá rẹ̀ lọ bá obìnrin náà, Sámúsìn sì se àsè ńlá kan níbẹ̀, torí bí àwọn ọ̀dọ́kùnrin ṣe máa ń ṣe nìyẹn. 11 Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n mú àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó tí wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n (30) wá, tí wọ́n máa wà lọ́dọ̀ rẹ̀. 12 Sámúsìn wá sọ fún wọn pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fún yín. Tí ẹ bá já a tí ẹ sì sọ ìdáhùn rẹ̀ fún mi láàárín ọjọ́ méje tí a máa fi jẹ àsè yìí, màá fún yín ní ọgbọ̀n (30) aṣọ ọ̀gbọ̀* àti ọgbọ̀n (30) ẹ̀wù. 13 Àmọ́ tí ẹ ò bá lè sọ ìdáhùn rẹ̀ fún mi, ẹ máa fún mi ní ọgbọ̀n (30) aṣọ ọ̀gbọ̀ àti ọgbọ̀n (30) ẹ̀wù.” Wọ́n sọ fún un pé: “Pa àlọ́ rẹ fún wa; a fẹ́ gbọ́.” 14 Ó wá sọ fún wọn pé:
“Látinú ohun tó ń jẹ nǹkan ni oúnjẹ ti wá,
Látinú alágbára sì ni ohun tó dùn ti wá.”+
Wọn ò rí àlọ́ náà já fún ọjọ́ mẹ́ta. 15 Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n sọ fún ìyàwó Sámúsìn pé: “Tan ọkọ rẹ+ kó lè sọ ìdáhùn àlọ́ náà fún wa. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, a máa dáná sun ìwọ àti ilé bàbá rẹ. Ṣé torí àtigba ohun ìní wa lẹ ṣe pè wá síbí ni?” 16 Ìyàwó Sámúsìn bá bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún sí i lọ́rùn, ó sì sọ pé: “Ó dájú pé o kórìíra mi; o ò nífẹ̀ẹ́ mi.+ O pa àlọ́ kan fún àwọn èèyàn mi, àmọ́ o ò sọ ìdáhùn rẹ̀ fún mi.” Ló bá sọ fún un pé: “Mi ò sọ fún bàbá àti ìyá mi pàápàá! Ṣé ó wá yẹ kí n sọ ọ́ fún ọ?” 17 Síbẹ̀ kò yéé sunkún sí i lọ́rùn fún ọjọ́ tó kù nínú àsè ọlọ́jọ́ méje náà. Níkẹyìn, ó sọ ọ́ fún un ní ọjọ́ keje, torí pé ó ti fòòró ẹ̀mí rẹ̀. Obìnrin náà sì lọ já àlọ́+ náà fún àwọn èèyàn rẹ̀. 18 Torí náà, kí oòrùn tó wọ̀* ní ọjọ́ keje, àwọn ọkùnrin ìlú náà sọ fún un pé:
“Kí ló dùn ju oyin lọ,
Kí ló sì lágbára ju kìnnìún lọ?”+
Ó fún wọn lésì pé:
“Ká ní ẹ ò fi ọmọ màlúù mi túlẹ̀ ni,+
Ẹ ò bá má lè rí ìdáhùn sí àlọ́ mi.”
19 Ẹ̀mí Jèhófà wá fún un lágbára,+ ó sì lọ sí Áṣíkẹ́lónì,+ ó ṣá ọgbọ̀n (30) nínú àwọn ọkùnrin wọn balẹ̀, ó sì bọ́ aṣọ wọn, ó wá kó àwọn aṣọ náà fún àwọn tó já àlọ́ náà.+ Inú ń bí i gidigidi bó ṣe ń gòkè pa dà lọ sí ilé bàbá rẹ̀.
20 Wọ́n wá fi ìyàwó Sámúsìn+ fún ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀.+