Diutarónómì
8 “Ẹ rí i pé ẹ̀ ń tẹ̀ lé gbogbo àṣẹ tí mò ń pa fún yín lónìí, kí ẹ lè máa wà láàyè,+ kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì wọ ilẹ̀ tí Jèhófà búra nípa rẹ̀ fún àwọn baba ńlá yín kí ẹ lè gbà á.+ 2 Máa rántí ọ̀nà jíjìn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ mú ọ rìn ní aginjù fún ogójì (40) ọdún yìí,+ kó lè rẹ̀ ọ́ sílẹ̀, kó sì dán ọ wò,+ kó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ,+ bóyá wàá pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ tàbí o ò ní pa wọ́n mọ́. 3 Torí náà, ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀, ó jẹ́ kí ebi pa ọ́,+ ó sì fi mánà bọ́ ọ,+ oúnjẹ tí o kò mọ̀, tí àwọn bàbá rẹ ò sì mọ̀, kí o lè mọ̀ pé kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè, àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu Jèhófà jáde ni èèyàn fi ń wà láàyè.+ 4 Aṣọ tí o wọ̀ ò gbó, ẹsẹ̀ rẹ ò sì wú jálẹ̀ ogójì (40) ọdún yìí.+ 5 O mọ̀ dáadáa lọ́kàn rẹ pé bí bàbá ṣe ń tọ́ ọmọ rẹ̀ sọ́nà ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń tọ́ ọ sọ́nà.+
6 “Torí náà, o gbọ́dọ̀ máa pa àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ mọ́, nípa rírìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀, kí o sì máa bẹ̀rù rẹ̀. 7 Torí ilẹ̀ dáradára ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń mú ọ lọ,+ ilẹ̀ tí omi ti ń ṣàn,* tí omi ti ń sun jáde, tí omi sì ti ń tú jáde* ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ní agbègbè olókè, 8 ilẹ̀ tí àlìkámà* àti ọkà bálì kún inú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn igi àjàrà, igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pómégíránétì,+ ilẹ̀ tí òróró ólífì àti oyin kún inú rẹ̀,+ 9 ilẹ̀ tí oúnjẹ ò ti ní wọ́n ọ, tó ò sì ní ṣaláìní ohunkóhun, ilẹ̀ tí irin wà nínú àwọn òkúta rẹ̀, tí wàá sì máa wa bàbà látinú àwọn òkè rẹ̀.
10 “Tí o bá ti jẹun, tí o sì ti yó, kí o yin Jèhófà Ọlọ́run rẹ lógo torí ilẹ̀ dáradára tó fún ọ.+ 11 Kí o má bàa gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run rẹ, rí i pé o pa àwọn òfin rẹ̀, ìdájọ́ rẹ̀ àti àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, èyí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí. 12 Tí o bá ti jẹun, tí o sì ti yó, tí o ti kọ́ àwọn ilé tó rẹwà, tí o sì ń gbé níbẹ̀,+ 13 tí ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti agbo ẹran rẹ di púpọ̀, tí fàdákà àti wúrà rẹ pọ̀ sí i, tí gbogbo ohun ìní rẹ sì pọ̀ rẹpẹtẹ, 14 má ṣe gbéra ga nínú ọkàn rẹ,+ kó sì mú kí o gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run rẹ tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú,+ 15 ẹni tó mú ọ rin inú aginjù tí ó tóbi tó sì ń bani lẹ́rù,+ tó ní àwọn ejò olóró àti àwọn àkekèé, tí ilẹ̀ ibẹ̀ gbẹ tí kò sì lómi. Ó mú kí omi ṣàn jáde látinú akọ àpáta,+ 16 ó sì fi mánà bọ́ ọ+ nínú aginjù, èyí tí àwọn bàbá rẹ ò mọ̀, kó lè rẹ̀ ọ́ sílẹ̀,+ kó sì dán ọ wò, kó lè ṣe ọ́ láǹfààní lọ́jọ́ ọ̀la.+ 17 Tí o bá sọ lọ́kàn rẹ pé, ‘Agbára mi àti iṣẹ́ ọwọ́ mi ló sọ mí di ọlọ́rọ̀,’+ 18 rántí pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ ló fún ọ lágbára láti di ọlọ́rọ̀,+ kó lè mú májẹ̀mú rẹ̀ tó bá àwọn baba ńlá rẹ dá ṣẹ, bó ṣe rí lónìí.+
19 “Tí ẹ bá gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run yín pẹ́nrẹ́n, tí ẹ wá ń tọ àwọn ọlọ́run míì lẹ́yìn, tí ẹ̀ ń sìn wọ́n, tí ẹ sì ń forí balẹ̀ fún wọn, mo ta kò yín lónìí pé ó dájú pé ẹ máa pa run.+ 20 Bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà máa pa run níwájú yín, bẹ́ẹ̀ lẹ ṣe máa pa run, torí ẹ ò fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín.+