Ìsíkíẹ́lì
4 “Ìwọ ọmọ èèyàn, gbé bíríkì kan, kí o sì gbé e síwájú rẹ. Ya àwòrán Jerúsálẹ́mù sórí rẹ̀. 2 Dó tì í,+ fi iyẹ̀pẹ̀ mọ odi yí i ká,+ mọ òkìtì láti dó tì í,+ pàgọ́ yí i ká, kí o sì gbé àwọn igi tí wọ́n fi ń fọ́ ògiri+ yí i ká. 3 Gbé agbada onírin, kí o sì fi ṣe ògiri onírin láàárín ìwọ àti ìlú náà. Kí o wá dojú kọ ọ́, kí a sì dó tì í; ìwọ ni kí o dó tì í. Àmì ni èyí jẹ́ fún ilé Ísírẹ́lì.+
4 “Kí o wá fi ẹ̀gbẹ́ rẹ òsì dùbúlẹ̀, kí o sì di ẹ̀bi ilé Ísírẹ́lì ru ara rẹ.*+ Iye ọjọ́ tí o bá fi dùbúlẹ̀ ni wàá fi ru ẹ̀bi wọn. 5 Èmi yóò sì mú kí o fi irínwó dín mẹ́wàá (390) ọjọ́ ru ẹ̀bi ilé Ísírẹ́lì,+ èyí tó dọ́gba pẹ̀lú iye ọdún tí wọ́n fi jẹ̀bi. 6 O sì gbọ́dọ̀ lo ọjọ́ náà pé.
“Lẹ́ẹ̀kan sí i, ìwọ yóò fi ẹ̀gbẹ́ rẹ ọ̀tún dùbúlẹ̀, ìwọ yóò sì di ẹ̀bi ilé Júdà+ ru ara rẹ fún ogójì (40) ọjọ́. Ọjọ́ kan fún ọdún kan, ọjọ́ kan fún ọdún kan ni mo là kalẹ̀ fún ọ. 7 Ìwọ yóò sì yíjú sí Jerúsálẹ́mù láti dó tì í,+ láìfi aṣọ bo apá rẹ, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí rẹ̀.
8 “Wò ó! èmi yóò fi okùn dè ọ́, kí o má bàa yí ẹ̀gbẹ́ rẹ pa dà, títí ìwọ yóò fi parí ọjọ́ tí wàá fi dó tì í.
9 “Kí o sì mú àlìkámà,* ọkà bálì, ẹ̀wà pàkálà, ẹ̀wà lẹ́ńtìlì, jéró àti ọkà sípẹ́ẹ̀tì, kí o kó wọn sínú ìkòkò kan, kí o sì fi wọ́n ṣe búrẹ́dì tí wàá jẹ. Iye ọjọ́ tí o fi ẹ̀gbẹ́ rẹ dùbúlẹ̀ ni wàá fi jẹ ẹ́, ìyẹn irínwó dín mẹ́wàá (390) ọjọ́.+ 10 Ìwọ yóò wọn oúnjẹ tí ó tó ogún (20) ṣékélì,* òun sì ni wàá máa jẹ lójúmọ́. Ó ní àkókò tí wàá máa jẹ ẹ́.
11 “Ṣe ni wàá máa wọn omi tí o fẹ́ mu, ìdá mẹ́fà òṣùwọ̀n hínì* lo máa wọ̀n. Tí àkókò bá tó ni wàá mu ún.
12 “O máa jẹ ẹ́ bí ìgbà tí ò ń jẹ búrẹ́dì ribiti tí wọ́n fi ọkà bálì ṣe; ojú wọn lo ti máa ṣe é, wàá sì fi ìgbẹ́ èèyàn dá iná rẹ̀, èyí tó ti gbẹ.” 13 Jèhófà wá sọ pé: “Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe máa jẹ oúnjẹ wọn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí màá fọ́n wọn ká sí nìyẹn, oúnjẹ àìmọ́ ni wọ́n máa jẹ.”+
14 Ní mo bá sọ pé: “Rárá o, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Láti kékeré títí di báyìí, mi* ò jẹ òkú ẹran rí tàbí ẹran tí wọ́n fà ya+ tó máa sọ mí di aláìmọ́, mi ò sì jẹ ẹran kankan tó jẹ́ aláìmọ́* rí.”+
15 Ó sọ fún mi pé: “Ó dáa, màá jẹ́ kí o lo ìgbẹ́ màlúù dípò ti èèyàn, òun lo sì máa fi dá iná tí wàá fi ṣe búrẹ́dì.” 16 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, mi ò ní jẹ́ kí oúnjẹ wà* ní Jerúsálẹ́mù,+ ṣe ni wọ́n máa wọn búrẹ́dì tí wọ́n fẹ́ jẹ látinú ìwọ̀nba tí wọ́n ní,+ ọkàn wọn ò sì ní balẹ̀. Wọ́n máa wọn omi tí wọ́n fẹ́ mu látinú ìwọ̀nba tí wọ́n ní, ẹ̀rù á sì máa bà wọ́n.+ 17 Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ yìí máa jẹ́ kí ẹnu yà wọ́n, bí wọ́n ṣe ń wo ara wọn, ẹ̀ṣẹ̀ wọn á sì mú kí wọ́n ṣègbé torí pé wọn ò ní búrẹ́dì àti omi tí ó tó.