Àìsáyà
Ẹni tí mo fẹ́ràn ní ọgbà àjàrà kan síbi òkè tó lọ́ràá.
2 Ó gbẹ́ ibẹ̀, ó sì kó àwọn òkúta ibẹ̀ kúrò.
Ó gbin àjàrà pupa tó dáa sínú rẹ̀,
Ó kọ́ ilé gogoro sí àárín rẹ̀,
Ó sì gbẹ́ ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì sínú rẹ̀.+
Ó wá ń retí pé kí àjàrà náà so,
Àmọ́ èso àjàrà igbó nìkan ló mú jáde. +
3 “Ní báyìí, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerúsálẹ́mù àti ẹ̀yin èèyàn Júdà,
Ẹ jọ̀ọ́, ẹ ṣèdájọ́ láàárín èmi àti ọgbà àjàrà mi.+
Nígbà tí mo retí pé kó so èso àjàrà,
Kí ló dé tó jẹ́ àjàrà igbó nìkan ló ń mú jáde?
5 Ó yá, ẹ jọ̀ọ́, ẹ jẹ́ kí n sọ fún yín,
Ohun tí màá ṣe sí ọgbà àjàrà mi:
Màá mú ọgbà tó yí i ká kúrò,
Màá sì dáná sun ún.+
Màá fọ́ ògiri olókùúta rẹ̀,
Wọ́n sì máa tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.
7 Torí pé ilé Ísírẹ́lì ni ọgbà àjàrà Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun;+
Àwọn èèyàn Júdà sì ni oko* tó fẹ́ràn.
8 Àwọn tó ń ní ilé kún ilé gbé +
Àti àwọn tí wọ́n ń ní ilẹ̀ kún ilẹ̀,+
Títí kò fi sí àyè mọ́,
Tó sì wá ku ẹ̀yin nìkan lórí ilẹ̀ náà!
9 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti búra ní etí mi,
Pé ọ̀pọ̀ ilé, bí wọ́n tiẹ̀ tóbi, tí wọ́n sì rẹwà,
Wọ́n máa di ohun àríbẹ̀rù,
Láìsí olùgbé kankan.+
10 Torí pé òṣùwọ̀n báàtì* kan ṣoṣo ni éékà ilẹ̀ mẹ́wàá* tí wọ́n gbin àjàrà sí máa mú jáde,
Eéfà* kan ṣoṣo sì ni irúgbìn tó jẹ́ òṣùwọ̀n hómérì* kan máa mú jáde.+
11 Àwọn tó ń dìde mu ọtí láàárọ̀ kùtù gbé,+
Tí wọ́n ń dúró síbẹ̀ dìgbà tílẹ̀ ṣú títí ọtí fi ń pa wọ́n!
12 Wọ́n ní háàpù àti ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín,
Ìlù tanboríìnì, fèrè àti wáìnì sì wà níbi àsè wọn;
Àmọ́ wọn ò ronú nípa iṣẹ́ Jèhófà,
Wọn ò sì rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
13 Torí náà, àwọn èèyàn mi máa lọ sí ìgbèkùn,
Torí wọn ò ní ìmọ̀;+
Ebi máa pa àwọn èèyàn wọn tó lọ́lá,+
Òùngbẹ sì máa gbẹ gbogbo èèyàn wọn gidigidi.
14 Torí náà, Isà Òkú* ti fẹ ara* rẹ̀ sí i,
Ó sì ti la ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbayawu láìní ààlà;+
Ó dájú pé iyì rẹ̀,* ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn rẹ̀ tí wọ́n ń pariwo àtàwọn èèyàn rẹ̀ tó ń ṣe àríyá aláriwo
Máa sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú rẹ̀.
15 Èèyàn sì máa tẹrí ba,
A máa rẹ èèyàn sílẹ̀,
A sì máa rẹ ojú àwọn agbéraga wálẹ̀.
16 Ìdájọ́* Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa gbé e ga,
Ọlọ́run tòótọ́, Ẹni Mímọ́,+ máa fi òdodo+ sọ ara rẹ̀ di mímọ́.
17 Àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn sì máa jẹko bíi pé ibi ìjẹko wọn ni;
Àwọn àjèjì máa jẹun níbi tó ti dahoro táwọn ẹran tí wọ́n bọ́ dáadáa ti jẹun.
18 Àwọn tó ń fi okùn ẹ̀tàn fa ẹ̀bi wọn lọ gbé,
Tí wọ́n sì ń fi okùn kẹ̀kẹ́ ẹṣin fa ẹ̀ṣẹ̀ wọn;
19 Àwọn tó ń sọ pé: “Kó jẹ́ kí iṣẹ́ Rẹ̀ yára kánkán;
Kó tètè dé, ká lè rí i.
20 Àwọn tó ń sọ pé ohun tó dára burú àti pé ohun tó burú dára gbé,+
Àwọn tó ń fi òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀, tí wọ́n sì ń fi ìmọ́lẹ̀ dípò òkùnkùn,
Àwọn tó ń fi ìkorò dípò adùn àti adùn dípò ìkorò!
22 Àwọn akọni nídìí ọtí mímu gbé
Àti àwọn tó mọ àdàlù ọtí ṣe dáadáa,+
23 Àwọn tó dá ẹni burúkú láre torí àbẹ̀tẹ́lẹ̀,+
Tí wọn ò sì jẹ́ kí olódodo rí ìdájọ́ òdodo gbà!+
24 Torí náà, bí ahọ́n iná ṣe máa ń jó àgékù pòròpórò run,
Tí koríko gbígbẹ sì máa ń rún sínú ọwọ́ iná,
Gbòǹgbò wọn gangan máa jẹra,
Ìtànná wọn sì máa fọ́n ká bí eruku,
Torí pé wọ́n kọ òfin* Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,
Wọn ò sì ka ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì sí.+
25 Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi bínú gidigidi sí àwọn èèyàn rẹ̀,
Ó sì máa na ọwọ́ rẹ̀ lòdì sí wọn, ó máa lù wọ́n.+
Àwọn òkè máa mì tìtì,
Òkú wọn sì máa dà bí ààtàn lójú ọ̀nà.+
Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí pa dà,
Àmọ́ ó ṣì na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lù wọ́n.
26 Ó ti gbé àmì sókè* sí orílẹ̀-èdè tó wà lọ́nà jíjìn;+
Ó ti súfèé sí wọn pé kí wọ́n wá láti àwọn ìkángun ayé;+
Sì wò ó! wọ́n ń yára bọ̀.+
27 Kò rẹ ẹnì kankan nínú wọn, wọn ò sì kọsẹ̀.
Ìkankan nínú wọn ò tòògbé, wọn ò sì sùn.
Àmùrè tó wà ní ìbàdí wọn ò tú,
Okùn bàtà wọn ò sì já.
28 Gbogbo ọfà wọn mú,
Wọ́n sì ti fa gbogbo ọrun wọn.*
Pátákò àwọn ẹṣin wọn dà bí akọ òkúta,
Àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ wọn sì dà bí ìjì.+
Wọ́n máa kùn, wọ́n sì máa mú ẹran,
Wọ́n á gbé e lọ, kò sì ní sẹ́ni tó máa gbà á lọ́wọ́ wọn.
30 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa kùn lórí rẹ̀,
Bí òkun ṣe ń ru.+