Àìsáyà
“Wò ó! Damásíkù ò ní jẹ́ ìlú mọ́,
Ó sì máa di àwókù.+
2 A máa pa àwọn ìlú Áróérì tì; +
Wọ́n máa di ibi tí àwọn agbo ẹran ń dùbúlẹ̀ sí
Ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.
3 Àwọn ìlú olódi ò ní sí mọ́ ní Éfúrémù,+
Ìjọba ò sì ní sí mọ́ ní Damásíkù;+
Àwọn tó ṣẹ́ kù lára Síríà
Sì máa dà bí ògo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,”* ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
5 Ó máa dà bí ìgbà tí ẹni tó ń kórè bá ń kó ọkà tó wà ní ìdúró jọ,
Tí apá rẹ̀ sì ń kórè ṣírí ọkà,
6 Èéṣẹ́ nìkan ló máa ṣẹ́ kù,
Bí ìgbà tí wọ́n lu igi ólífì:
Ólífì méjì tàbí mẹ́ta tó pọ́n nìkan ló ṣẹ́ kù lórí ẹ̀ka tó ga jù,
Mẹ́rin tàbí márùn-ún nìkan lórí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tó ń so èso,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí.
7 Ní ọjọ́ yẹn, èèyàn máa yíjú sókè wo Aṣẹ̀dá rẹ̀, ojú rẹ̀ á sì máa wo Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì. 8 Kò ní wo àwọn pẹpẹ,+ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀;+ kò sì ní tẹjú mọ́ ohun tó fi ìka rẹ̀ ṣe, ì báà jẹ́ àwọn òpó òrìṣà* tàbí àwọn pẹpẹ tùràrí.
9 Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ìlú ààbò rẹ̀ máa dà bí ibi tí wọ́n pa tì lórí ilẹ̀ tí igi pọ̀ sí,+
Bí ẹ̀ka tí wọ́n pa tì níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì;
Ó máa di ahoro.
11 Ní ọ̀sán, o rọra ṣe ọgbà yí oko rẹ ká,
Ní àárọ̀, o mú kí irúgbìn rẹ rú jáde,
Àmọ́ ìkórè ò ní sí ní ọjọ́ àìsàn àti ìrora tí kò ṣeé wò sàn.+
12 Fetí sílẹ̀! Ọ̀pọ̀ èèyàn ń fa rúkèrúdò,
Wọ́n ń pariwo bí omi òkun tó ń ru gùdù!
Àwọn orílẹ̀-èdè ń hó yèè,
Ìró wọn dà bí ariwo alagbalúgbú omi!
13 Ìró àwọn orílẹ̀-èdè máa dà bí ariwo omi púpọ̀.
Ó máa bá wọn wí, wọ́n sì máa sá lọ jìnnà réré,
Wọ́n á sá lọ bí ìgbà tí atẹ́gùn ń fẹ́ ìyàngbò* lórí àwọn òkè,
Bí ẹ̀gún* tí ìjì ń gbé yípo yípo.
14 Ìbẹ̀rù wà ní ìrọ̀lẹ́.
Kó tó di àárọ̀, wọn ò sí mọ́.
Ìpín àwọn tó ń kó wa lẹ́rù nìyí,
Ohun tó sì máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ń kó ohun ìní wa nìyí.