Àìsáyà
27 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà, tòun ti idà rẹ̀ tó mú, tó tóbi, tó sì lágbára,+
Máa yíjú sí Léfíátánì,* ejò tó ń yọ́ bọ́rọ́,
Sí Léfíátánì, ejò tó ń lọ́,
Ó sì máa pa ẹran ńlá tó wà nínú òkun.
2 Ní ọjọ́ yẹn, ẹ kọrin fún obìnrin náà* pé:
“Ọgbà àjàrà tí wáìnì rẹ̀ ń yọ ìfófòó!+
Gbogbo ìgbà ni mò ń bomi rin ín.+
Mò ń dáàbò bò ó tọ̀sántòru,
Kí ẹnikẹ́ni má bàa ṣe é léṣe.+
Ta ló máa wá fi àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún àti èpò bá mi jagun?
Gbogbo wọn ni màá tẹ̀ mọ́lẹ̀, tí màá sì dáná sun pa pọ̀.
5 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó rọ̀ mọ́ ibi ààbò mi.
Kó wá bá mi ṣàdéhùn àlàáfíà;
Àní kó wá àlàáfíà pẹ̀lú mi.”
6 Lọ́jọ́ iwájú, Jékọ́bù máa ta gbòǹgbò,
Ísírẹ́lì máa yọ ìtànná, ó máa rú jáde,+
Wọ́n sì máa fi irè oko kún ilẹ̀ náà.+
7 Ṣé dandan ni kí a fi ẹgba ẹni tó ń lù ú nà án ni?
Àbí ṣé dandan ni kí a pa á bí àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n pa?
8 Igbe tó ń dẹ́rù bani lo máa fi bá a fà á nígbà tí o bá lé e lọ.
Atẹ́gùn rẹ̀ tó le ló máa fi lé e jáde ní ọjọ́ afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn.+
9 Torí náà, báyìí la ṣe máa ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ Jékọ́bù,+
Èyí sì ni ohun tó máa jèrè lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nígbà tí a bá mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kúrò:
Ó máa ṣe gbogbo òkúta pẹpẹ
10 Torí wọ́n máa pa ìlú olódi tì;
Wọ́n máa pa àwọn ibi ìjẹko tì, wọ́n á sì fi í sílẹ̀ bí aginjù.+
Ibẹ̀ ni ọmọ màlúù á ti máa jẹko, tó sì máa dùbúlẹ̀ sí,
Ó sì máa jẹ àwọn ẹ̀ka rẹ̀.+
Torí àwọn èèyàn yìí ò ní òye.+
Ìdí nìyẹn tí Aṣẹ̀dá wọn ò fi ní ṣàánú wọn rárá,
Ẹni tó dá wọn ò sì ní ṣojúure kankan sí wọn.+
12 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà máa lu èso jáde láti Odò* tó ń ṣàn títí dé Àfonífojì Íjíbítì,+ a sì máa kó yín jọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì.+ 13 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa fun ìwo ńlá kan,+ àwọn tó ń ṣègbé lọ ní ilẹ̀ Ásíríà+ àti àwọn tó fọ́n ká ní ilẹ̀ Íjíbítì+ máa wá, wọ́n á sì forí balẹ̀ fún Jèhófà ní òkè mímọ́, ní Jerúsálẹ́mù.+