Àìsáyà
29 “O gbé ìwọ Áríélì,* Áríélì, ìlú tí Dáfídì pàgọ́ sí!+
Ẹ máa bá a lọ lọ́dọọdún;
Ẹ máa ṣe àwọn àjọyọ̀+ ní àkókò wọn.
2 Àmọ́ màá mú ìdààmú bá Áríélì,+
Ó máa ṣọ̀fọ̀, ó máa dárò,+
Ó sì máa dà bí ibi ìdáná pẹpẹ Ọlọ́run fún mi.+
Ohùn rẹ á máa jáde látinú ilẹ̀+
Bí ohùn abẹ́mìílò,
Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ á sì máa dún ṣíoṣío látinú iyẹ̀pẹ̀.
Ó sì máa ṣẹlẹ̀ lójijì, ká tó ṣẹ́jú pẹ́.+
6 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa fún ọ láfiyèsí
Pẹ̀lú ààrá, ìmìtìtì ilẹ̀ àti ariwo ńlá,
Pẹ̀lú ìjì, atẹ́gùn líle àti ọwọ́ iná tó ń jẹni run.”+
7 Gbogbo orílẹ̀-èdè tó pọ̀ rẹpẹtẹ tí wọ́n ń gbógun ja Áríélì,+
Gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbógun jà á,
Àwọn ilé gogoro tí wọ́n fi dó tì í,
Àti àwọn tó ń kó ìdààmú bá a,
Máa wá dà bí àlá, ìran òru.
8 Àní, ó máa dà bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa lá àlá pé òun ń jẹun,
Àmọ́ tó jí, tí ebi ṣì ń pa á*
Àti bí ìgbà tí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ lá àlá pé òun ń mu omi,
Àmọ́ tó jí, tó ti rẹ̀ ẹ́, tí òùngbẹ ṣì ń gbẹ ẹ́.*
Bó ṣe máa rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè tó pọ̀ rẹpẹtẹ nìyí,
Àwọn tó gbógun ja Òkè Síónì.+
Wọ́n ti yó, àmọ́ kì í ṣe wáìnì ni wọ́n mu yó;
Wọ́n ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́, àmọ́ kì í ṣe ọtí ló ń mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.
10 Torí Jèhófà ti da ẹ̀mí oorun àsùnwọra lù yín;+
Ó ti pa ojú yín dé, ẹ̀yin wòlíì,+
Ó sì ti bo orí yín, ẹ̀yin aríran.+
11 Gbogbo ìran dà bí ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a gbé èdìdì lé fún yín.+ Tí wọ́n bá fún ẹni tó mọ̀wé kà, tí wọ́n sọ pé: “Jọ̀ọ́, kà á sókè,” á sọ pé: “Mi ò lè kà á, torí wọ́n ti gbé èdìdì lé e.” 12 Tí wọ́n bá sì fún ẹni tí kò mọ̀wé kà ní ìwé náà, tí wọ́n sọ pé: “Jọ̀ọ́, kà á,” á sọ pé: “Mi ò lè kàwé rárá.”
13 Jèhófà sọ pé: “Àwọn èèyàn yìí ń fi ẹnu wọn sún mọ́ mi,
Wọ́n sì ń fi ètè wọn bọlá fún mi,+
Àmọ́ ọkàn wọn jìnnà gan-an sí mi;
Àṣẹ èèyàn tí wọ́n kọ́ wọn ló sì ń mú kí wọ́n máa bẹ̀rù mi.+
14 Torí náà, èmi ni Ẹni tó tún máa ṣe àwọn ohun àgbàyanu sí àwọn èèyàn yìí,+
Ohun àgbàyanu kan tẹ̀ lé òmíràn;
Ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n wọn máa ṣègbé,
Òye àwọn olóye wọn sì máa fara pa mọ́.”+
15 Ó mà ṣe o, fún àwọn tó sapá gidigidi kí wọ́n lè fi ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe* pa mọ́ fún Jèhófà.+
16 Ẹ wo bí ẹ ṣe ń dorí nǹkan kodò!*
Ṣé ojú kan náà ló yẹ ká fi wo amọ̀kòkò àti amọ̀?+
Ṣé ó yẹ kí ohun tí a dá sọ nípa ẹni tó dá a pé:
“Òun kọ́ ló dá mi”?+
Ṣé ohun tí a ṣe sì máa ń sọ fún ẹni tó ṣe é pé:
“Kò fi òye hàn”?+
18 Ní ọjọ́ yẹn, àwọn adití máa gbọ́ ọ̀rọ̀ inú ìwé náà,
Àwọn afọ́jú sì máa ríran látinú ìṣúdùdù àti òkùnkùn.+
19 Àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ máa yọ̀ gidigidi nínú Jèhófà,
Àwọn tó sì jẹ́ aláìní láàárín àwọn èèyàn máa yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.+
20 Torí pé ìkà èèyàn kò ní sí mọ́,
Òpin máa dé bá afọ́nnu,
Gbogbo àwọn tó sì wà lójúfò láti ṣe ìkà máa pa run,+
21 Àwọn tó ń fi ọ̀rọ̀ èké dá àwọn míì lẹ́bi,
Tí wọ́n ń dẹ pańpẹ́ sílẹ̀ de olùgbèjà* ní ẹnubodè ìlú+
Àti àwọn tó ń jiyàn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti fi ìdájọ́ òdodo du olódodo.+
22 Torí náà, ohun tí Jèhófà, ẹni tó ra Ábúráhámù pa dà,+ sọ fún ilé Jékọ́bù nìyí: