Àìsáyà
31 Ó mà ṣe fún àwọn tó ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ Íjíbítì o,+
Tí wọ́n gbójú lé ẹṣin,+
Tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé kẹ̀kẹ́ ogun, torí pé wọ́n pọ̀,
Àti àwọn ẹṣin ogun,* torí pé wọ́n lágbára.
Wọn ò yíjú sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,
Wọn ò sì wá Jèhófà.
2 Àmọ́ òun náà gbọ́n, ó sì máa mú àjálù wá,
Kò sì ní kó ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ jẹ.
Ó máa dìde sí ilé àwọn tó ń ṣe ohun tó burú
Àti sí àwọn tó ń ran aṣebi lọ́wọ́.+
3 Àmọ́ èèyàn lásán ni àwọn ará Íjíbítì, wọn kì í ṣe Ọlọ́run;
Ẹran ara ni àwọn ẹṣin wọn ní, wọn kì í ṣe ẹ̀mí.+
Tí Jèhófà bá na ọwọ́ rẹ̀,
Ẹnikẹ́ni tó bá ranni lọ́wọ́ máa kọsẹ̀,
Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá sì ràn lọ́wọ́ máa ṣubú;
Gbogbo wọn máa ṣègbé lẹ́ẹ̀kan náà.
4 Torí ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí:
“Bí kìnnìún, ìyẹn ọmọ kìnnìún tó lágbára,* ṣe ń kùn lórí ẹran tó pa,
Nígbà tí a pe odindi àwùjọ àwọn olùṣọ́ àgùntàn sí i,
Tí ohùn wọn ò dẹ́rù bà á,
Tí gìrìgìrì wọn ò sì kó jìnnìjìnnì bá a,
Bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa sọ̀ kalẹ̀ wá ja ogun
Lórí Òkè Síónì àti lórí òkè kékeré rẹ̀.
5 Bí àwọn ẹyẹ tó ń já ṣòòrò wálẹ̀, ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ṣe máa gbèjà Jerúsálẹ́mù.+
Ó máa gbèjà rẹ̀, ó sì máa gbà á là.
Ó máa dá a sí, ó sì máa gbà á sílẹ̀.”
6 “Ẹ pa dà sọ́dọ̀ Ẹni tí ẹ fi àfojúdi ṣọ̀tẹ̀ sí, ẹ̀yin èèyàn Ísírẹ́lì.+ 7 Torí pé ní ọjọ́ yẹn, kálukú máa kọ àwọn ọlọ́run rẹ̀ tí kò ní láárí, tó fi fàdákà ṣe àti àwọn ọlọ́run rẹ̀ tí kò wúlò, tó fi wúrà ṣe, èyí tí ẹ fi ọwọ́ ara yín ṣe, tó sì jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
Ó máa sá lọ nítorí idà,
Wọ́n sì máa fipá kó àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́.