Àìsáyà
58 “Fi gbogbo ẹnu kígbe; má ṣe dákẹ́!
Gbé ohùn rẹ sókè bíi fèrè.
Kéde ọ̀tẹ̀ àwọn èèyàn mi fún wọn,+
Kí o sọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jékọ́bù fún wọn.
2 Wọ́n ń wá mi lójoojúmọ́,
Inú wọn sì ń dùn láti mọ àwọn ọ̀nà mi,
Bíi pé orílẹ̀-èdè olódodo ni wọ́n,
Tí kò sì pa ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run wọn tì.+
Wọ́n béèrè ìdájọ́ òdodo lọ́wọ́ mi,
Inú wọn ń dùn láti sún mọ́ Ọlọ́run:+
3 ‘Kí ló dé tí o ò rí i nígbà tí à ń gbààwẹ̀?+
Kí ló sì dé tí o ò kíyè sí i nígbà tí à ń pọ́n ara* wa lójú?’+
4 Aáwọ̀ àti ìjà ló máa ń gbẹ̀yìn ààwẹ̀ yín,
Ẹ sì ń gbáni ní ẹ̀ṣẹ́ ìkà.
Ẹ ò lè gbààwẹ̀ bí ẹ ṣe ń ṣe lónìí, kí a sì gbọ́ ohùn yín ní ọ̀run.
5 Ṣé ó yẹ kí ààwẹ̀ tí mo fọwọ́ sí rí báyìí,
Bí ọjọ́ tí èèyàn máa pọ́n ara* rẹ̀ lójú,
Tó máa dorí kodò bí koríko etídò,
Kó ṣe ibùsùn rẹ̀ sórí aṣọ ọ̀fọ̀* àti eérú?
Ṣé ohun tí ẹ̀ ń pè ní ààwẹ̀ àti ọjọ́ tínú Jèhófà dùn sí nìyí?
6 Rárá, ààwẹ̀ tí mo fọwọ́ sí nìyí:
Kí ẹ tú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ìkà,
Kí ẹ tú ìdè ọ̀pá àjàgà,+
Kí ẹ tú ẹni tí ìyà ń jẹ sílẹ̀,+
Kí ẹ sì kán gbogbo ọ̀pá àjàgà sí méjì;
7 Ẹ fún ẹni tí ebi ń pa lára oúnjẹ yín,+
Kí ẹ mú aláìní àti ẹni tí kò rílé gbé wá sínú ilé yín,
Kí ẹ fi aṣọ bo ẹni tó wà ní ìhòòhò tí ẹ bá rí i,+
Kí ẹ má sì kẹ̀yìn sí àwọn èèyàn yín.
Òdodo rẹ á máa lọ níwájú rẹ,
Ògo Jèhófà á sì máa ṣọ́ ọ láti ẹ̀yìn.+
9 O máa pè, Jèhófà sì máa dáhùn;
O máa kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ó sì máa sọ pé, ‘Èmi nìyí!’
Tí o bá mú ọ̀pá àjàgà kúrò láàárín rẹ,
Tí o kò na ìka rẹ, tí o kò sì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ mọ́,+
10 Tí o bá fún ẹni tí ebi ń pa ní ohun tí ìwọ fúnra rẹ* fẹ́,+
Tí o sì tẹ́ àwọn* tí ìyà ń jẹ lọ́rùn,
Ìmọ́lẹ̀ rẹ máa tàn nínú òkùnkùn pàápàá,
Ìṣúdùdù rẹ sì máa dà bí ọ̀sán gangan.+
11 Jèhófà á máa darí rẹ nígbà gbogbo,
Ó sì máa tẹ́ ọ* lọ́rùn, kódà ní ilẹ̀ gbígbẹ;+
Ó máa mú kí egungun rẹ lágbára,
O sì máa dà bí ọgbà tí wọ́n ń bomi rin dáadáa,+
Bí ìsun omi, tí omi rẹ̀ kì í tán.
12 Wọ́n máa tún àwọn àwókù àtijọ́ kọ́ nítorí rẹ,+
O sì máa dá ìpìlẹ̀ àwọn ìran tó ti kọjá pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀.+
Wọ́n máa pè ọ́ ní ẹni tó ń tún àwọn ògiri tó ti fọ́ ṣe,*+
Ẹni tó ń ṣe àtúnṣe àwọn ọ̀nà tí wọ́n á máa gbé.
13 Tí o kò bá wá* ire ara rẹ* ní ọjọ́ mímọ́ mi, nítorí Sábáàtì,+
Tí o sì pe Sábáàtì ní ohun tó ń múnú ẹni dùn gidigidi, ọjọ́ mímọ́ Jèhófà, ọjọ́ tó yẹ ká ṣe lógo,+
Tí o sì ṣe é lógo dípò kí o máa wá ire ara rẹ, kí o sì máa sọ ọ̀rọ̀ tí kò nítumọ̀,
14 Nígbà náà, inú rẹ máa dùn gidigidi torí Jèhófà,
Màá sì mú kí o gun àwọn ibi tó ga ní ayé.+