Àìsáyà
63 Ta ló ń bọ̀ láti Édómù+ yìí,
Tó ń bọ̀ láti Bósírà,+ tó wọ aṣọ tí àwọ̀ rẹ̀ ń tàn yòò,*
Tó wọ aṣọ tó dáa gan-an,
Tó ń yan bọ̀ nínú agbára ńlá rẹ̀?
“Èmi ni, Ẹni tó ń fi òdodo sọ̀rọ̀,
Ẹni tó lágbára gan-an láti gbani là.”
2 Kí ló dé tí aṣọ rẹ pọ́n,
Kí ló sì dé tí ẹ̀wù rẹ dà bíi ti ẹni tó ń tẹ àjàrà ní ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì?+
3 “Èmi nìkan ni mo tẹ wáìnì nínú ọpọ́n.
Ìkankan nínú àwọn èèyàn náà ò sí lọ́dọ̀ mi.
Mò ń fi ìbínú tẹ̀ wọ́n ṣáá,
Mo sì ń fi ìrunú tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.+
Ẹ̀jẹ̀ wọn ta sára ẹ̀wù mi,
Ó sì ti yí gbogbo aṣọ mi.
5 Mo wò, àmọ́ kò sẹ́ni tó ṣèrànwọ́;
Ẹnu yà mí pé kò sẹ́ni tó tì mí lẹ́yìn.
7 Màá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Jèhófà ṣe torí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,
Àwọn iṣẹ́ Jèhófà tó yẹ ká yìn,
Torí gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa,+
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun rere tó ti ṣe fún ilé Ísírẹ́lì,
Nínú àánú rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ tó lágbára.
8 Torí ó sọ pé: “Ó dájú pé èèyàn mi ni wọ́n, àwọn ọmọ tí kò ní di aláìṣòótọ́.”*+
Ó wá di Olùgbàlà wọn.+
9 Nínú gbogbo ìdààmú wọn, ìdààmú bá òun náà.+
Ìránṣẹ́ òun fúnra rẹ̀* sì gbà wọ́n là.+
10 Àmọ́ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i,+ wọ́n sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.+
11 Wọ́n rántí àwọn ìgbà àtijọ́,
Àwọn ọjọ́ Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀:
“Ẹni tó mú wọn jáde látinú òkun dà,+ àwọn àti àwọn olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran rẹ̀?+
Ẹni tó fi ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀ sínú rẹ̀ dà,+
12 Ẹni tó mú kí apá Rẹ̀ ológo bá ọwọ́ ọ̀tún Mósè lọ,+
Ẹni tó pín omi níyà níwájú wọn,+
Kó lè ṣe orúkọ tó máa wà títí láé fún ara rẹ̀,+
13 Ẹni tó mú kí wọ́n rìn gba inú omi tó ń ru gùdù,*
Tó fi jẹ́ pé wọ́n rìn láìkọsẹ̀,
Bí ẹṣin ní ìgbèríko?*
A ti fà wọ́n sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi.
Bí Ábúráhámù ò tiẹ̀ mọ̀ wá,
Tí Ísírẹ́lì ò sì dá wa mọ̀,
Ìwọ Jèhófà, ni Bàbá wa.
Olùtúnrà wa látìgbà àtijọ́ ni orúkọ rẹ.+
17 Jèhófà, kí ló dé tí o gbà ká* rìn gbéregbère kúrò ní àwọn ọ̀nà rẹ?
Kí ló dé tí o gbà kí* ọkàn wa le, tí a ò fi bẹ̀rù rẹ?+
Pa dà, torí àwọn ìránṣẹ́ rẹ,
Àwọn ẹ̀yà ogún rẹ.+
18 Ó jẹ́ ti àwọn èèyàn mímọ́ rẹ fúngbà díẹ̀.
Àwọn ọ̀tá wa ti tẹ ibi mímọ́ rẹ mọ́lẹ̀.+
19 Ó pẹ́ gan-an tí a ti dà bí àwọn tí o kò ṣàkóso wọn rí,
Bí àwọn tí a ò fi orúkọ rẹ pè rí.