Jóṣúà
1 Lẹ́yìn ikú Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà, Jèhófà sọ fún Jóṣúà*+ ọmọ Núnì, ìránṣẹ́+ Mósè pé: 2 “Mósè ìránṣẹ́ mi ti kú.+ Gbéra, kí o sọdá Jọ́dánì, ìwọ àti gbogbo èèyàn yìí, kí ẹ sì lọ sí ilẹ̀ tí mo fẹ́ fún wọn, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 3 Màá fún yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ yín tẹ̀, bí mo ṣe ṣèlérí fún Mósè.+ 4 Ilẹ̀ yín máa jẹ́ láti aginjù títí dé Lẹ́bánónì àti odò ńlá, ìyẹn odò Yúfírétì, gbogbo ilẹ̀ àwọn ọmọ Hétì,+ títí lọ dé Òkun Ńlá* ní ìwọ̀ oòrùn.*+ 5 Kò sẹ́ni tó máa lè dìde sí ọ ní gbogbo ìgbà tí o bá fi wà láàyè.+ Bí mo ṣe wà pẹ̀lú Mósè ni màá ṣe wà pẹ̀lú rẹ.+ Mi ò ní pa ọ́ tì, mi ò sì ní fi ọ́ sílẹ̀.+ 6 Jẹ́ onígboyà àti alágbára,+ torí ìwọ lo máa mú kí àwọn èèyàn yìí jogún ilẹ̀ tí mo búra fún àwọn baba ńlá wọn pé màá fún wọn.+
7 “Ṣáà rí i pé o jẹ́ onígboyà àti alágbára gidigidi, kí o sì rí i pé ò ń tẹ̀ lé gbogbo Òfin tí Mósè ìránṣẹ́ mi pa láṣẹ fún ọ. Má yà kúrò nínú rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì,+ kí o lè máa hùwà ọgbọ́n níbikíbi tí o bá lọ.+ 8 Ìwé Òfin yìí kò gbọ́dọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ,+ kí o máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà á* tọ̀sántòru, kí o lè rí i pé ò ń tẹ̀ lé gbogbo ohun tí wọ́n kọ sínú rẹ̀;+ ìgbà yẹn ni ọ̀nà rẹ máa yọrí sí rere, tí wàá sì máa hùwà ọgbọ́n.+ 9 Ṣebí mo ti pàṣẹ fún ọ? Jẹ́ onígboyà àti alágbára. Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, má sì jáyà, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí o bá lọ.”+
10 Jóṣúà wá pàṣẹ fún àwọn olórí àwọn èèyàn náà pé: 11 “Ẹ lọ káàkiri ibùdó, kí ẹ sì pa àṣẹ yìí fún àwọn èèyàn náà pé, ‘Ẹ ṣètò oúnjẹ sílẹ̀, torí ní ọjọ́ mẹ́ta òní, ẹ máa sọdá Jọ́dánì láti lọ gba ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín pé kó di tiyín.’”+
12 Jóṣúà sọ fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè pé: 13 “Ẹ rántí ohun tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà pa láṣẹ fún yín pé:+ ‘Jèhófà Ọlọ́run yín máa fún yín ní ìsinmi, ó sì ti fún yín ní ilẹ̀ yìí. 14 Àwọn ìyàwó yín, àwọn ọmọ yín àtàwọn ẹran ọ̀sìn yín á máa gbé ní ilẹ̀ tí Mósè fún yín ní apá ibí yìí* ní Jọ́dánì,+ àmọ́ kí gbogbo ẹ̀yin jagunjagun tó lákíkanjú+ sọdá ṣáájú àwọn arákùnrin yín, kí ẹ tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti jagun.+ Kí ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ 15 títí Jèhófà fi máa fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi, bó ṣe ṣe fún yín, tí àwọn náà á sì gba ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún wọn. Kí ẹ wá pa dà sí ilẹ̀ tí wọ́n fún yín pé kí ẹ máa gbé, kí ẹ sì gbà á, ilẹ̀ tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà fún yín ní ìlà oòrùn Jọ́dánì.’”+
16 Wọ́n dá Jóṣúà lóhùn pé: “A máa ṣe gbogbo ohun tí o pa láṣẹ fún wa, a sì máa lọ sí ibikíbi tí o bá rán wa.+ 17 Bí a ṣe fetí sí gbogbo ohun tí Mósè sọ gẹ́lẹ́ la máa fetí sí ọ. Kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣáà ti wà pẹ̀lú rẹ bó ṣe wà pẹ̀lú Mósè.+ 18 Ṣe la máa pa ẹnikẹ́ni tó bá tàpá sí àṣẹ rẹ, tí kò sì tẹ̀ lé gbogbo ohun tí o bá pa láṣẹ fún un.+ Ìwọ ṣáà ti jẹ́ onígboyà àti alágbára.”+