Hósíà
3 Mo mọ Éfúrémù,
Ísírẹ́lì kì í sì í ṣe àjèjì sí mi.
4 Ìṣe wọn kò jẹ́ kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run wọn,
Torí ẹ̀mí ìṣekúṣe* wà ní àárín wọn;+
Wọn ò sì ka Jèhófà sí.
5 Ìwà Ísírẹ́lì ti jẹ́rìí sí i* pé ó gbéra ga;+
Àṣìṣe Ísírẹ́lì àti Éfúrémù ti mú kí wọ́n kọsẹ̀,
Júdà sì ti kọsẹ̀ pẹ̀lú wọn.+
6 Agbo ẹran wọn àti ọ̀wọ́ ẹran wọn ni wọ́n fi ń wá Jèhófà,
Ṣùgbọ́n wọn kò rí i.
Ó ti kúrò lọ́dọ̀ wọn.+
7 Wọ́n ti hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà,+
Torí wọ́n ti bí àwọn ọmọ àjèjì.
Ní báyìí, kò ní ju oṣù kan lọ tí àwọn àti ìpín* wọn á fi pa run.
8 Ẹ fun ìwo+ ní Gíbíà àti kàkàkí ní Rámà! +
Ẹ kígbe ogun ní Bẹti-áfénì,+ a ó tẹ̀ lé ọ, ìwọ Bẹ́ńjámínì!
9 Éfúrémù, ìwọ yóò di ohun àríbẹ̀rù ní ọjọ́ ìjìyà.+
Mo ti sọ ohun tó dájú pé ó máa ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.
10 Àwọn olórí Júdà dà bí àwọn tó ń sún ààlà sẹ́yìn.+
Èmi yóò da ìbínú ńlá mi sórí wọn bí omi.
11 Éfúrémù rí ìdààmú, ó gba ìdájọ́ tó yẹ,
Nítorí ó ti pinnu láti tẹ̀ lé ọ̀tá rẹ̀.+
12 Torí náà, mo dà bí òólá* sí Éfúrémù
Mo sì dà bí ìdíbàjẹ́ sí ilé Júdà.
13 Nígbà tí Éfúrémù rí i pé òun ń ṣàìsàn, tí Júdà sì rí i pé egbò wà lára òun,
Éfúrémù lọ sí Ásíríà,+ ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá.
Ṣùgbọ́n kò lè mú un lára dá,
Kò sì lè wo egbò rẹ̀ sàn.
14 Màá dà bí ọmọ kìnnìún sí Éfúrémù
Àti bíi kìnnìún* alágbára sí ilé Júdà.
Èmi fúnra mi á fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, màá sì lọ;+
Màá gbé wọn lọ, kò sì sí ẹni tó máa gbà wọ́n sílẹ̀.+
15 Màá lọ, màá sì pa dà sí ipò mi títí wọ́n á fi gba ìyà ẹ̀bi wọn,
Nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìdààmú, wọ́n á wá mi.”+