Hósíà
Ó ti kọ lù wá, ṣùgbọ́n á di ọgbẹ́ wa.
2 Á mú wa sọ jí lẹ́yìn ọjọ́ méjì.
Á gbé wa dìde ní ọjọ́ kẹta,
A ó sì máa wà láàyè níwájú rẹ̀.
3 A ó mọ Jèhófà, a ó sì fi ìtara wá ìmọ̀ rẹ̀.
Jíjáde rẹ̀ dájú bí àfẹ̀mọ́jú;
Yóò wá bá wa bí ọ̀wààrà òjò,
Bí òjò ìgbà ìrúwé tó máa ń rin ilẹ̀.”
4 “Kí ni màá ṣe sí ọ̀rọ̀ rẹ, ìwọ Éfúrémù?
Kí ni màá sì ṣe sí ọ̀rọ̀ rẹ, ìwọ Júdà?
Nítorí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o sọ pé o ní dà bí ìkùukùu òwúrọ̀,
Àti bí ìrì tó tètè ń pòórá.
Ìdájọ́ lórí wọn yóò sì tàn bí ìmọ́lẹ̀.+
6 Nítorí pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀* ni inú mi dùn sí, kì í ṣe ẹbọ
Àti ìmọ̀ nípa Ọlọ́run dípò odindi ẹbọ sísun.+
7 Ṣùgbọ́n bí èèyàn lásán-làsàn, wọ́n ti tẹ májẹ̀mú lójú.+
Wọ́n ti hùwà àìṣòótọ́ sí mi ní ilẹ̀ wọn.
9 Ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà dà bí àwọn jàǹdùkú* tó lúgọ de ẹnì kan.
Wọ́n ń pa èèyàn lójú ọ̀nà ní Ṣékémù,+
Torí pé ìwà àìnítìjú ni wọ́n ń hù.
10 Mo ti rí ohun tó burú jáì ní ilé Ísírẹ́lì.
11 Àmọ́, ìwọ Júdà, a ti dá àkókò ìkórè fún ọ,
Nígbà tí mo bá kó àwọn èèyàn mi tó wà ní oko ẹrú pa dà.”+