Ẹ́sítà
6 Ní òru ọjọ́ yẹn, ọba ò rí oorun sùn.* Torí náà, ó ní kí wọ́n mú ìwé àkọsílẹ̀ ìtàn àwọn àkókò+ wá, wọ́n sì kà á fún ọba. 2 Nínú àkọsílẹ̀ náà, wọ́n rí ohun tí Módékáì sọ nípa Bígítánà àti Téréṣì, àwọn òṣìṣẹ́ méjì láàfin ọba tí wọ́n jẹ́ aṣọ́nà, àwọn tó gbìmọ̀ pọ̀ láti pa* Ọba Ahasuérúsì.+ 3 Ọba wá béèrè pé: “Ọlá àti iyì wo la ti fún Módékáì nítorí ohun tó ṣe yìí?” Àwọn ẹmẹ̀wà* ọba sọ pé: “A kò tíì ṣe nǹkan kan fún un.”
4 Lẹ́yìn náà, ọba sọ pé: “Ta ló wà ní àgbàlá?” Ní àkókò yìí, Hámánì ti dé sí àgbàlá ìta+ ilé* ọba láti sọ fún ọba bí wọ́n ṣe máa gbé Módékáì kọ́ sórí òpó igi tó ti ṣe fún un.+ 5 Àwọn ẹmẹ̀wà* ọba sọ fún un pé: “Hámánì+ ni, ó dúró ní àgbàlá.” Ọba wá sọ pé: “Ẹ jẹ́ kó wọlé.”
6 Nígbà tí Hámánì wọlé, ọba béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ló yẹ ká ṣe fún ọkùnrin tó wu ọba pé kó dá lọ́lá?” Hámánì sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: “Ta ni ọba tún fẹ́ dá lọ́lá tí kì í bá ṣe èmi?”+ 7 Nítorí náà, Hámánì sọ fún ọba pé: “Ní ti ọkùnrin tó wu ọba pé kó dá lọ́lá, 8 jẹ́ kí wọ́n mú ẹ̀wù oyè+ tí ọba máa ń wọ̀ àti ẹṣin tí ọba máa ń gùn, kí wọ́n sì fi ìwérí ọba sí orí ẹṣin náà. 9 Kí wọ́n fi ẹ̀wù oyè àti ẹṣin náà síkàáwọ́ ọ̀kan lára àwọn ìjòyè pàtàkì, kí wọ́n wọ aṣọ náà fún ọkùnrin tó wu ọba pé kó dá lọ́lá, kí wọ́n sì mú un gun ẹṣin náà ní gbàgede ìlú. Kí wọ́n máa kéde níwájú rẹ̀ pé: ‘Ohun tí wọ́n máa ń ṣe nìyí fún ẹni tó wu ọba pé kó dá lọ́lá!’”+ 10 Lójú ẹsẹ̀, ọba sọ fún Hámánì pé: “Ṣe kíá! Mú ẹ̀wù oyè àti ẹṣin náà, kí o sì ṣe ohun tí o sọ yìí fún Módékáì, Júù tó ń jókòó ní ẹnubodè ọba. Má yọ ìkankan sílẹ̀ nínú gbogbo ohun tí o sọ.”
11 Torí náà, Hámánì mú ẹ̀wù oyè àti ẹṣin náà, ó wọ aṣọ náà fún Módékáì,+ ó sì mú un gun ẹṣin ní gbàgede ìlú, ó ń kéde níwájú rẹ̀ pé: “Ohun tí wọ́n máa ń ṣe nìyí fún ẹni tó wu ọba pé kó dá lọ́lá!” 12 Lẹ́yìn náà, Módékáì pa dà sí ẹnubodè ọba, àmọ́ Hámánì yára lọ sí ilé rẹ̀, ó ń ṣọ̀fọ̀, ó sì bo orí rẹ̀. 13 Hámánì sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i fún Séréṣì+ aya rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Nígbà náà, àwọn amòye rẹ̀ àti Séréṣì aya rẹ̀ sọ fún un pé: “Tó bá jẹ́ pé àtọmọdọ́mọ* Júù ni Módékáì tí o ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣubú níwájú rẹ̀ yìí, á jẹ́ pé o ò ní borí rẹ̀; ó sì dájú pé wàá ṣubú níwájú rẹ̀.”
14 Bí wọ́n ṣe ń bá a sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àwọn òṣìṣẹ́ ààfin ọba dé, wọ́n sì yára mú Hámánì lọ síbi àsè tí Ẹ́sítà ti sè.+