Ẹ́sítà
9 Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, ìyẹn oṣù Ádárì,*+ nígbà tí ó tó àkókò láti mú ọ̀rọ̀ ọba àti òfin rẹ̀ ṣẹ,+ ní ọjọ́ tí àwọn ọ̀tá àwọn Júù ti dúró dè láti ṣẹ́gun wọn, ọ̀tọ̀ lohun tó ṣẹlẹ̀, àwọn Júù ṣẹ́gun àwọn tó kórìíra wọn.+ 2 Àwọn Júù kóra jọ ní àwọn ìlú wọn ní gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà lábẹ́ àṣẹ Ọba Ahasuérúsì,+ láti gbéjà ko àwọn tó fẹ́ ṣe wọ́n ní jàǹbá, kò sì sí ẹni tó lè dúró níwájú wọn, nítorí ẹ̀rù wọn ń ba gbogbo àwọn èèyàn.+ 3 Gbogbo àwọn olórí tó wà ní àwọn ìpínlẹ̀,* àwọn baálẹ̀,+ àwọn gómìnà àti àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ ọba ń ti àwọn Júù lẹ́yìn, torí ẹ̀rù Módékáì ń bà wọ́n. 4 Módékáì ti di alágbára+ ní ilé* ọba, òkìkí rẹ̀ sì ń kàn káàkiri gbogbo ìpínlẹ̀,* torí ńṣe ni agbára Módékáì ń pọ̀ sí i.
5 Àwọn Júù fi idà ṣá gbogbo àwọn ọ̀tá wọn balẹ̀, wọ́n ń pa wọ́n, wọ́n sì ń run wọ́n; wọ́n ṣe ohun tó wù wọ́n sí àwọn tó kórìíra wọn.+ 6 Ní Ṣúṣánì*+ ilé ńlá,* àwọn Júù pa ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọkùnrin, wọ́n sì run wọ́n. 7 Wọ́n tún pa Páṣáńdátà, Dálífónì, Ásípátà, 8 Pọ́rátà, Adalíà, Árídátà, 9 Pámáṣítà, Árísáì, Árídáì àti Fáísátà, 10 àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá Hámánì ọmọ Hamédátà, ọ̀tá àwọn Júù.+ Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n pa wọ́n, wọn ò kó ohun ìní èyíkéyìí.+
11 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n ròyìn iye àwọn tí wọ́n pa ní Ṣúṣánì* ilé ńlá* fún ọba.
12 Ọba sọ fún Ẹ́sítà Ayaba pé: “Ní Ṣúṣánì* ilé ńlá,* àwọn Júù ti pa ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin Hámánì mẹ́wẹ̀ẹ̀wá. Kí ni wọ́n ṣe ní àwọn ìpínlẹ̀ abẹ́ àṣẹ ọba yòókù?+ Ní báyìí, kí lohun tí o fẹ́ tọrọ? A ó fi fún ọ. Kí lo sì tún fẹ́ béèrè? A ó ṣe é fún ọ.” 13 Ẹ́sítà fèsì pé: “Tó bá dáa lójú ọba,+ jẹ́ kí a fún àwọn Júù tó wà ní Ṣúṣánì* láyè lọ́la láti ṣe ohun tí òfin ti òní sọ;+ sì jẹ́ kí wọ́n gbé àwọn ọmọkùnrin Hámánì mẹ́wẹ̀ẹ̀wá kọ́ sórí òpó igi.”+ 14 Torí náà, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n ṣe òfin kan ní Ṣúṣánì,* wọ́n sì gbé àwọn ọmọkùnrin Hámánì mẹ́wẹ̀ẹ̀wá kọ́.
15 Àwọn Júù tó wà ní Ṣúṣánì* tún kóra jọ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ádárì,+ wọ́n sì pa ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin ní Ṣúṣánì,* àmọ́ wọn ò kó ohun ìní èyíkéyìí.
16 Bákan náà, ìyókù àwọn Júù tó wà ní àwọn ìpínlẹ̀ abẹ́ àṣẹ ọba kóra jọ, wọ́n sì gbèjà ara* wọn.+ Wọ́n rẹ́yìn àwọn ọ̀tá wọn,+ ẹgbẹ̀rún márùnléláàádọ́rin (75,000) lára àwọn tó kórìíra wọn ni wọ́n pa; àmọ́ wọn ò kó ohun ìní èyíkéyìí. 17 Ọjọ́ kẹtàlá oṣù Ádárì ni èyí ṣẹlẹ̀, ní ọjọ́ kẹrìnlá, wọ́n sinmi, wọ́n sì fi ṣe ọjọ́ àsè àti ọjọ́ ayọ̀.
18 Àwọn Júù tó wà ní Ṣúṣánì* kóra jọ ní ọjọ́ kẹtàlá+ àti ní ọjọ́ kẹrìnlá,+ wọ́n sinmi ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún, wọ́n sì fi ṣe ọjọ́ àsè àti ọjọ́ ayọ̀. 19 Ìdí nìyẹn tí àwọn Júù ìgbèríko tó ń gbé ní àwọn ìlú tó wà ní àwọn agbègbè tó jìnnà ṣe fi ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ádárì ṣe ọjọ́ ayọ̀ àti ọjọ́ àsè, ọjọ́ àjọyọ̀ + àti àkókò láti fi oúnjẹ ránṣẹ́ sí ara wọn.+
20 Módékáì+ kọ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí sílẹ̀, ó sì fi àwọn lẹ́tà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù tó wà ní gbogbo ìpínlẹ̀ abẹ́ àṣẹ Ọba Ahasuérúsì, àwọn tó wà nítòsí àti àwọn tó wà lọ́nà jíjìn. 21 Ó sọ fún wọn pé kí wọ́n máa pa ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ádárì àti ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù náà mọ́ lọ́dọọdún, 22 torí ní àwọn ọjọ́ yẹn, àwọn Júù sinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, oṣù yẹn ni ìbànújẹ́ wọn di ayọ̀, tí ọ̀fọ̀+ wọn sì di àjọyọ̀. Ó ní kí wọ́n máa fi àwọn ọjọ́ náà ṣe ọjọ́ àsè àti ọjọ́ ayọ̀ àti àkókò láti fi oúnjẹ ránṣẹ́ sí ara wọn àti láti máa fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí àwọn aláìní.
23 Àwọn Júù gbà láti máa ṣe àjọyọ̀ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ náà lọ àti láti máa ṣe ohun tí Módékáì kọ ránṣẹ́ sí wọn. 24 Hámánì+ ọmọ Hamédátà, ọmọ Ágágì,+ ọ̀tá gbogbo àwọn Júù ti gbèrò láti pa àwọn Júù run,+ ó ti ṣẹ́ Púrì,+ ìyẹn Kèké, láti kó ìpayà bá wọn, kí ó sì pa wọ́n run. 25 Àmọ́ nígbà tí Ẹ́sítà wá síwájú ọba, ọba pa àṣẹ kan tí wọ́n kọ sílẹ̀ pé:+ “Kí èrò ibi tí ó gbà sí àwọn Júù+ pa dà sórí rẹ̀”; wọ́n sì gbé òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ́ sórí òpó igi.+ 26 Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pe àwọn ọjọ́ náà ní Púrímù, látinú orúkọ Púrì.*+ Nítorí gbogbo ohun tí wọ́n kọ sínú lẹ́tà yìí àti ohun tí wọ́n rí nípa ọ̀ràn yìí àti ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn, 27 àwọn Júù sọ ọ́ di dandan fún ara wọn àti fún àtọmọdọ́mọ wọn pẹ̀lú gbogbo àwọn tó dara pọ̀ mọ́ wọn+ láti máa ṣe ayẹyẹ ọjọ́ méjèèjì yìí láìjẹ́ kó yẹ̀, kí wọ́n sì máa ṣe ohun tó wà lákọsílẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ náà ní àkókò tí wọ́n bọ́ sí lọ́dọọdún. 28 Kí ìdílé kọ̀ọ̀kan, ìpínlẹ̀* kọ̀ọ̀kan àti ìlú kọ̀ọ̀kan máa rántí àwọn ọjọ́ yìí, kí wọ́n sì máa pa wọ́n mọ́ láti ìran dé ìran; àwọn ọjọ́ Púrímù yìí kò gbọ́dọ̀ yẹ̀ láàárín àwọn Júù, àwọn àtọmọdọ́mọ wọn sì gbọ́dọ̀ máa ṣe ìrántí wọn títí láé.
29 Ẹ́sítà Ayaba, ọmọ Ábíháílì àti Módékáì tó jẹ́ Júù fi gbogbo àṣẹ tí wọ́n ní kọ̀wé láti fìdí lẹ́tà kejì nípa Púrímù múlẹ̀. 30 Módékáì fi àwọn lẹ́tà tó ní ọ̀rọ̀ àlàáfíà àti òtítọ́ ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù ní ìpínlẹ̀* mẹ́tàdínláàádóje+ (127) tó wà lábẹ́ àkóso Ahasuérúsì,+ 31 láti fìdí pípa àwọn ọjọ́ Púrímù yìí mọ́ múlẹ̀ ní àkókò tí wọ́n bọ́ sí, gẹ́gẹ́ bí Módékáì tó jẹ́ Júù àti Ẹ́sítà Ayaba ṣe ní kí wọ́n ṣe+ àti bí wọ́n ṣe sọ ọ́ di dandan fún ara* wọn àti àwọn àtọmọdọ́mọ wọn láti máa ṣe é+ pẹ̀lú ààwẹ̀+ àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀.+ 32 Àṣẹ Ẹ́sítà fìdí ọ̀rọ̀ nípa Púrímù+ múlẹ̀, wọ́n sì kọ ọ́ sínú ìwé kan.